'Ìjọba fẹ́ pa wá lẹ́numọ́, wọn ní ka má sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù àwọn agbébọn tó jí èèyàn 177 gbé lọ ní ìlú wa'
Àwọn aráàlú Kurmin Wali ní ìjọba ìbílẹ̀ Kajuru, ìpínlẹ̀ Kaduna, níbi tí àwọn agbébọn ti jí èèyàn 177 gbé lọ́jọ́ Àìkú tó kọjá yìí, ti fẹ̀sùn kàn pé àwọn aláṣẹ ń gbìyànjú láti pa àwọn lẹ́nu mọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn èèyàn náà sọ fún BBC lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026 pé àwọn aláṣẹ ń sọ fún àwọn aráàlú pé kí wọ́n yé bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, tí wọn sì ń dènà àwọn akọ̀ròyìn láti wọ inú ìlú náà.
Aráàlú kan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun nítorí ààbò sọ pé àwọn aláṣẹ ṣèkìlọ̀ fáwọn aráàlú pé wọn kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ìkọlù náà fáwọn akọ̀ròyìn kankan.
BBC náà kò tètè ríbi wọ inú ìlú Kurmin Wali nítorí àwọn agbófinró àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà láti wọ inú ìlú náà ní kí a padà àmọ́ tí wọ́n padà jẹ́ kí a wọnú ìlú náà nígbà tí ikọ̀ ìròyìn wa kọ̀ láti padà.
Àwọn tí wọ́n jí àwọn èèyàn gbé àtàwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pé inú ìbànújẹ́ àti ìbẹ̀rù làwọn aráàlú wà láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé nítorí àìsí ààbò tó péya fún wọn.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Uba Sani padà ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Kurmin Wali lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ìkọlù náà wáyé tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pèsè ibùdó àwọn ọmọ ogun sí agbègbè náà.
Bákan náà ló tún kéde láti pèsè àwọn ohun ìdẹ̀kùn fáwọn tí wọ́n lùgbàdì ìkọlù àwọn agbébọn náà tó fi mọ́ pípèsè ètò ìlera fún wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àtàwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ Kajuru ti kọ́kọ́ jiyàn pé ìkọlù kò wáyé ní ìlú Kurmin Wali, kí wọ́n tó yí ohun padà.
Gómìnà Sani sọ pé àwọn èèyàn ṣi iléeṣẹ́ ọlọ́pàá gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà, tó sì fẹ̀sùn kàn pé àwọn èèyàn ti fẹ́ máa ti ọwọ́ òṣèlú bọ ìkọlù náà.
Ó fi kun pé akitiyan ti ń lọ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣàwárí gbogbo àwọn tó wà ní àhámọ́ ajínigbé náà.
Àwọn aláṣẹ kò ì tíì fi iye èèyàn tí wọ́n jí gbé léde.
Ikọ̀ kankan kò ì tíì jáde láti sọ pé àwọn ló ṣe ìkọlù náà ṣùgbọ́n ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí táwọn agbébọn ń ṣe irúfẹ́ ìkọlù báyìí ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Lóòótọ́ ni agbébọn jí àwọn èèyàn gbé ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Kaduna- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá yí ohùn padà
Lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti ni irọ ni awọn to sọ pe wọn ji awọn olujọsin gbe lọjọ Aiku niluu naa n pa, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti pada sọ pe ootọ ni ijinigbe ọlọpọ eeyan naa waye.
Tẹ ẹ ba ranti, ọjọ Aje ọsẹ yii ni iroyin ijinigbe naa gbode kan.
BBC fi to yin leti pe awọn ajinigbe wọ abule Kurmin Wali, nijọba ibilẹ Kajuru, ipinlẹ Kaduna, wọn si ji eeyan ti a gbọ pe ko din ni 170 gbe lọ ni awọn ile ijọsin onigbagbọ kan.
Koda, Emir ilu Kurmin Wali, Ishaku Dan'azumi, fidi ẹ mulẹ pe awọn ajinigbe naa wọ abule lọjọ Aiku, o ni wọn gbe eeyan to le lọgọjọ lọ.
Bakan naa ni Alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi (CAN) ẹka ti Kaduna, Ẹni ọwọ Joseph Hayab, naa fidi ijinigbe ọhun mulẹ lọjọ Aje.
Amọ gbogbo eyi ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Alhaji Muhammad Rabiu, sọ pe ko ri bẹẹ.
Alẹ ọjọ Aje naa ni kọmandi ọlọpaa Kaduna fi atẹjade lede, ti wọn ni iroyin ofege ni awọn ileeṣẹ iroyin gbe kalẹ nipa ijinigbe ọhun.
Wọn ni ẹni ti wọn ba ji eeyan rẹ gbe ko mu ẹri ijinigbe ọhun wa.
Ohun ti awọn ara abule Kajuri wi
Nigba ti wọn tun n fi ijinigbe yii mulẹ fun BBC, awọn olugbe Kurmin Wali sọ pe eeyan 177 ni wọn ji gbe ni ṣọọṣi mẹta.
Wọn ni mọkanla ninu wọn jajabọ, nigba ti eeyan ọgọjọ (160) ṣi wa nigbekun .
BBC ri iwe ti wọn kọ orukọ awọn eeyan ọgọjọ ti wọn lo wa nigbekun naa si, amọ ko ti I si iwadii kankan to fidi eyi mulẹ.
O ṣoju mi koro kan tilẹ sọ pe awọn eeyan kan fẹ sa mọ wọn lọwọ, amọ awọn ajinigbe naa ti yi gbogbo abule po lọjọ Aiku naa.
"Wọn ko awọn eeyan pọ, wọn si ko wọn wọgbo lọ."
Bẹẹ ni ara abule kan wi.
Nipa awọn ile ijọsin ti awọn agbebọn ọhun gbero lati kọlu, awọn ara abule sọ pe: Pentecostal Fellowship Assembly (PFA)akọkọ, Pentecostal Fellowship Assembly (PFA) ikeji, ati Evangelical Church Winning All (ECWA) ni.
Bawo lo ṣe tun jẹ ti ọlọpaa yi ohùn pada?
Lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Alukoro ọlọpaa Naijiria, Benjamin Hundeyin, fi atẹjade kan sita.
Ninu atẹjade naa lo ti ni igbimọ to n ri si aabo ni Kaduna ṣepade lẹyin ti wọn gbọ iroyin naa.
Hundeyin sọ pe ohun ti Kọmiṣanna ọlọpaa Kaduna sọ ṣaaju wa fun kawọn eeyan ma baa ko aya soke ni, ki i ṣe pe o sọ pe wọn ko ji eeyan gbe.
" Ọrọ tawọn eeyan n ṣigbọ yii ki I ṣe pe a sọ pe iṣẹlẹ naa ko waye, ṣugbọn lati ṣọra, ka si ri okodoro gbamu lati ibẹ ni, titi kan orukọ ati iye eeyan ti iṣẹlẹ naa kan."
Atẹjade Hundeyin lo sọ bẹẹ.
Hundeyin ṣalaye pe iwadii ti ẹka ọtẹlẹmuyẹ ṣe fi han pe wọn ji awọn eeyan gbe.
Hundeyin ko sọ iye eeyan ti wọn ji gbe, amọ o ni awọn ti da awọn agbofinro si Kajuru lati yi ibẹ ka.
O ni iṣẹ wọn ni lati ṣawari ibi ti awọn to wa nigbekun wa, ki ri wọn gba pada wale, ki alaafia si pada si agbegbe naa.
Àwọn eeyan koro oju si ọlọpaa
Latari ai tete gba pe ododo ni wọn ji awọn eeyan gbe yii, ọpọ eeyan titi kan awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ lo ti n koro oju si ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.
Ajọ Amnesty International jẹ ọkan lara awọn to ti bu ẹnu atẹ lu ọlọpaa , wọn ni wọn fẹẹ dawọ bo otitọ mọlẹ ni.
"Awọn alaṣẹ wa gbọdọ tete gbe igbesẹ lati dẹkun bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe lọpọ yanturu yii, eyi to ti n di iṣẹlẹ gbogbo igba ni Naijiria."
Bẹẹ ni Amnesty International wi.
Wọn ni awọn oloyun ati ọmọde wa lara awọn ti ajinigbe gbe lọ lasiko ijọsin lọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii.
Ṣé lóòótọ́ ni agbébọn jí èèyàn 177 lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì ní Kaduna?
Oríṣun àwòrán, AFP
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ ni igboro pe awọn ajinigbe ji eeyan to le ni ọgọrun gbe lọ nini ile ijọsin kan niluu Kajuru.
Ọrọ naa lo jẹyọ lasiko ti kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Muhammad Rabiu, n ba awọn akọroyin sọrọ.
O ni awọn kọlọrọsi ẹda kan lo n gbe iroyin naa kiri lati mọọmọ da ipaya si ọkan awọn eeyan ipinlẹ naa.
Kọmiṣọna ọhun tun fi akoko naa kilọ fun awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri ki wọn ṣọ ara wọn, bi bẹẹ kọ, wọn yoo foju wina ofin.
Nibi ipade naa ni alaga ijọba ibilẹ Kajuru, Dauda Madaki, ti fi kun irọ ni iroyin naa pe ko si ohun to jọ ijinigbe lagbegbe ọhun rara.
O ni "A ṣabẹwo si ṣọọṣi ti wọn ni wọn ti ji awọn eeyan gbe ṣugbọn a ko ri apẹrẹ nnkankan to jọ bẹẹ rara.
"Mo bere lọwọ olori ilu naa, Mai Dan Zaria, nipa iṣẹlẹ ọhun, oun naa sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
"Mo tun ke pe olori ọdọ agbegbe naa, Bernard Bona, oun naa to ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe irọ ni."
Lẹyin naa lo sọ pe ki ẹnikẹni to ba ni ẹri pe wọn ji awọn eeyan gbe lọ nibẹ mu eri wa, ki wọn si fi orukọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ṣọwo si ijọba.
Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ipinlẹ ọhun ti kọkọ sọ ninu atẹjade kan pe wọn ji olujọsin to le ni ọgọrun gbe lọ nibẹ.
Ọkan lara awọn olori ilu naa tun sọ fun BBC pe asiko ti isin n lọ lọwọ ni awọn agbesunmọmi ya bo ile ijọsin kan nibẹ ti wọn si ji eeyan 177 gbe lọ, amọ awọn mọkanla moribọ ninu wọn.
Èèyàn 160 ni agbébọn gbé ní ṣọ́ọ̀ṣì – CAN
Gẹgẹ bi ajọ Christian Association Of Nigeria (CAN), ẹka Kaduna ṣe ṣalaye iṣẹlẹ naa, wọn ni awọn ṣọọṣi naa wa ni abule Kurmin Wali, nijọba ibilẹ Kajuru, ipinlẹ Kaduna.
CAN Kaduna sọ pe lasiko ti awọn eeyan n jọsin lọwọ ni awọn ajinigbe ọhun ya de ti wọn si n gbe wọn jade wọgbo lọ.
Akọwe apapọ fun ẹgbẹ CAN ni Kaduna, Ẹni ọwọ Joseph John Hayab, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ fun ẹka AFP lọjọ Aje, sọ pe:
"Bo tilẹ jẹ pe mi o fẹ sọ pato iye eeyan ti awọn agbebọn naa gbe lọ, ohun ti mo gbọ lati agbegbe naa ni pe o to eeyan mejilelaadọsan-an (172) ti wọn ji gbe lọ.
"Ṣugbọn awọn mẹsan-an ninu wọn ti rọna sa wale, nigba ti eeyan 163 ṣi wa nibẹ ti a n wa."
"Awọn to ṣekọlu naa yade pupọ, wọn si di ẹnu ọna abawọle awọn ṣọọṣi naa, wọn si n fipa gbe awọn olujọsin wọnu igbo lọ."
Ẹni ọwọ Hayab sọ pe ohun yowu to le mu awọn agbebọn naa ji awọn eeyan lọ bi eyi ko ni I mu awọn dẹyin.
"A ko ni i juwọ silẹ, a maa tẹsiwaju lati maa sowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo ati ijọba lati ri i pe a ri awọn eeyan to wa nigbekun naa gba."
Àwọn ṣọọṣi wo ni wọn doju kọ?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ijinigbe naa waye ni nnkan bii aago mọkanla kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn, laaarọ ọjọ isinmi, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii.
Abule Kurmin Wali to ti waye yii si jẹ igbo kan ni Kajuru, ipinlẹ Kaduna.
Awọn ile ijọsin ti wọn doju sọ bi a ṣe gbọ ni Evangelical Church Winning All (ECWA), ṣọọṣi Katoliiki kan ati ijọ Kerubu ati Serafu kan.
Nipa awọn to ṣe ikọlu ọhun, agbebọn to dihamọra ogun ni wọn pe wọn.
Awọn nnkan ija igbalode ni wọn si lo.
Iroyin sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa Kaduna ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn wọn ko ti i fi iye eeyan to wa nigbekun lede lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Tẹ o ba gbagbe, ni oṣu Kọkanla ọdun 2025, o le ni ọọdunrun (300) akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe nile ẹkọ Katoliiki St Mary, Papiri, nipinlẹ Niger.
Bẹẹ ni agbebọn ji awọn akẹkọọ gbe ni Kebbi, wọn ṣọṣẹ nipinlẹ Kwara pẹlu, bi wọn ṣe ji awọn eeyan gbe ni wọn pa awọn miran, ki ijọba too kede pe oun ti fi ilana asọye (Non Kinetic) yanju rẹ, ti awọn to wa nigbekun si pada sile wọn.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available