'Májèlé ni wọ́n fún Destiny Boy jẹ, kò kú sílé babaláwo'

Oloogbe Destiny Boy

Oríṣun àwòrán, Oloogbe Destiny /Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Lati igba ti iku akọrin Fuji, Afeez Adeshina ti ọpọ mọ si Destiny Boy ti gbode lọjọ Aiku ni oniruuru awuyewuye ti n jade lori ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ile babalawo kan ni akọrin naa ku si ni awọn mii n sọ pe ile iwosan kan ni o ku si.

Amọ ẹgbọn ọdọmọkunrin naa ti wa jade sọrọ lori ohun to ṣokunfa iku Destiny Boy.

Ninu fidio kan ti obinrin naa gbe sori ayelujara nibi to ti n sunkun sọ pe awọn nnkan tawọn eeyan n sọ nipa aburo oun naa kii ṣe ootọ gẹgẹ bi wọn ṣe n gbe kiri.

O ni aburo oun ko ku sile babalawo gẹgẹ bi iroyin to gba ori ayelujara.

Bakan naa lo ni ko lọ ṣe oogun owo gẹgẹ bi awọn iroyin to n tan lori ayelujara.

O fẹsun kan pe awọn kan lo fun aaburo oun ni majele jẹ amọ ko darukọ awọn to fun Destiny Boy ni majele jẹ.

"Ẹ ro ikunlẹ abiyamọ ninu gbogbo nnkan ti ẹ n sọ, Afeez kere si oun to ṣe e yii o."

"Ko ṣogun owo, ko ku sile babalawo, ko ṣẹṣo owo o."

Iya Destiny sọrọ, ọmọ mi dawo ra mọto ni, ko ṣe oṣolẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu fidio kan lori ayelujara, Saida Adeshina ti i ṣe Iya Oloogbe Destiny Boy, sọrọ to tako ohun ti awọn eeyan n gbe kiri.

Iya Destiny Boy ṣalaye ninu fidio naa pe:

" Destiny Boy lọ sinmi ni. Igba to bi akọbi ẹ ni nnkan bii ọdun meji sẹyin ni wahala yẹn bẹrẹ.

" Oba Edu lo ni ko waa gba ẹran ikomọ,nibi ti oun ati baba ẹ ti n lọ lo ti diwọ mọri to de ṣubu, bo ṣe bẹrẹ niyẹn.

"Ogun oru, to maa n ṣe wọn bii warapa lo n ṣe Destiny Boy, a kan maa n bo o nitori gbajumọ to jẹ ni.

"Oba Edu dẹ fẹran ẹ bii ọmọ ni, oun lo maa n ba wa tọju ẹ nitori aisan yii."

Iya Destiny tẹsiwaju pe aisan naa lo ṣe ọmọ oun to fi wa nile Oba Edu, to n tọju rẹ.

O ni Ọba Edu fun un ni ẹrọ, nigba ti ko yatọ ni wọn gbe e lọ sọsibitu, ọsibitu naa lo ni Destiny Boy ku si, ki i ṣe ile babalawo.

" Isọkusọ ti awọn ọmọ Naijiria n sọ kiri yẹn, mo maa tan imọlẹ si i. Ọmọ mi ko ku silee babalawo, wọn gbe e lọ sileewosan, nigba ti ẹmi fẹẹ bọ lo pọ aisan to n ṣe e jade yẹn.

" Ti awọn ololofẹ ẹ ba ri i loju agbo ti ko daraya, aisan yẹn lo fa a. Ki i ṣe pe o gbe ọja.

"Moto olowo nla ti wọn n sọ pe o ra, o dawo ra mọto yẹn ni, o ti n dawo mọto naa tipẹ, ko ṣoogun owo, ko ṣe oṣolẹ"

Lakootan alaye rẹ, Iya Oloogbe ni Oba Edu kọ lo pa ọmọ oun, koda, babalawo to fẹran rẹ bii ẹmi naa sunkun lori iku Destiny Boy bo ṣe sọ.

Awuyewuye lórí ikú tó pa Destiny Boy, ṣé lóòótọ́ ló kú sílé e babaláwo?

Oloogbe Afeez Adeshina, Destiny Boy

Oríṣun àwòrán, Destiny Boy/Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Afeez Adeshina, Destiny Boy

To ba ṣe pe ijamba mọto tabi ki eeyan sun ko ma si ji mọ lo pa Afeez Adeshina (Destiny Boy) ti okiki iku rẹ gbode yii ni, boya iku naa ko ba ma la ariwo ati awuyewuye lọ bi eyi to rinlẹ gidi lasiko yii.

Lati ana ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ti iroyin iku Destiny Boy ti gbode, ni ọpọ awuyewuye ti n jade lori iku ọmọ ọdun mejilelogun (22) naa.

Idi ariwo ọhun ko ṣẹyin ibi ti wọn ni Destiny Boy ku si, ohun to gba ori ayelujara kan ni pe ile babalawo to n ṣoogun fun un ni ọmọdekunrin naa dakẹ si.

Koda, awọn kan sọ pe wọn ko wulẹ gbe e lọ sileewosan rara lẹyin ti iṣẹ ti babalawo ọhun ṣe fun un yiwọ tan.

Ohun to n lọ kiri lori ayelujara ni pe awure ọla nla, iṣẹ to ju ọjọ ori ọmọ naa lọ ni babalawo yii n ṣe fun un tipẹ, nitori ati le gunke ọla ju bẹẹ lọ.

Wọn ni ọdọ awo naa lo ti ko si wahala to fa iku rẹ yii, ibẹ naa ni wọn gbe e lọ nigba to n pọkaka iku, ibẹ naa lo si ti bẹrẹ si i pọ ẹjẹ lẹnu titi to fi dagbere faye.

Ṣugbọn awọn kan sọ pe ko ri bẹẹ.

Wọn ni loootọ lo jẹ pe ile alawo rẹ ni wọn kọkọ gbe e lọ, ṣugbọn nigba ti nnkan ọhun fẹẹ yiwọ, wọn sare gbe e lọ sileewosan.

Awọn wọnyi sọ pe ileewosan ni Destiny Boy pada dakẹ si, ki wọn too gbe oku rẹ lọ sin si Abeokuta.

Ta a ni Babalawo Destiny Boy gan-an?

Ọmọwe Ifayomi Oba Edu Jogbodo Orunmila, Oba Awurela Agbaye Obatala (Babalawo to ṣẹ Ifa fun Destiny Boy)

Oríṣun àwòrán, Alore TV

Àkọlé àwòrán, Ọmọwe Ifayomi Oba Edu Jogbodo Orunmila, Oba Awurela Agbaye Obatala

Lati mọ otitọ to wa nidii iku Destiny Boy ati ibi to ku si, BBC News Yoruba ṣe iwadii, a si ri i pe Ọmọwe Ifayomi Oba Edu Jogbodo Orunmila, Oba Awurela Agbaye Obatala, ni Babalawo to n ṣiṣẹ fun Destiny Boy.

Ilu Arigbajo, nitosi Ifo, nipinle Ogun ni Awo Ifayomi Oba Edu fi ikalẹ si.

Yatọ si Destiny Boy, a gbọ pe ọpọ olorin Fuji ni Oba Edu tun maa n ṣiṣẹ fun, ti wọn si maa n lọ sọdọ rẹ daadaa.

Lori iku Destiny Boy yii, BBC News Yoruba pe Oba Edu lori aago laaarọ oni ti i se Monde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii, lati mọ ajọṣepọ aarin oun ati Oloogbe Destiny Boy, ati pe ṣe ọdọ rẹ ni ọmọ naa ku si loootọ.

Nigba to n dahun ipe naa, ẹni to gbe e sọ pe amugbalẹgbẹẹ, (P.A) Oba Edu Ifayomi ni oun.

O ni ka jẹ koun lọọ gbe foonu fun baba funra rẹ lati dahun ibeere wa.

Ṣugbọn bo ṣe gbe foonu naa lọ ni ẹnikẹni ko sọrọ mọ, ti akọroyin wa ko si gbọ ohun Oba Edu tabi ti amugbalẹgbẹẹ rẹ naa mọ.

Lẹyin eyi ni akọroyin wa pe pada, ṣugbọn ko kẹsẹ jari.

A fi atẹjiṣẹ ohùn (voicenote) ranṣẹ pẹlu, ṣugbọn wọn ko fesi titi ti a fi pari iroyin yii.

"Awọn Obi Destiny Boy mọ pe Oba Edu n ṣiṣẹ fun ọmọ wọn, koda, wọn jọ maa n lọ sibẹ ni"

Ẹnikan to sunmọ Iya Destiny Boy, to si mu Oloogbe paapaa bii ọmọ, ṣalaye fun BBC lori ajọṣepọ babalawo naa, ọmọ to ku ati awọn obi rẹ.

Iya to ni ka ma darukọ oun naa sọ pe awọn obi Destiny Boy mọ pe o maa n lọ ṣe oogun lọdọ Oba Edu.

Koda, o ni ọpọ igba ni babalawo rẹ yii ti lo nnkan fun un loju awon obi rẹ, ti wọn yoo tun gbe e si ori ayelujara.

"Awọn iṣẹ ti wọn maa n fi ọti lile lo, atawọn nnkan mi-in ni Oba Edu maa n fun Destiny Boy lo loju awọn obi rẹ, wọn yoo tun gbe fidio rẹ si ori ayelujara paapaa.

" O ya mi lẹnu pe baba rẹ le maa sunkun bayii pe Oba Edu ṣeka fun Destiny Boy, wọn ti ba a lọ sọdọ babalawo naa bii ẹẹmẹta ti mo si mọ si i daadaa.''

Bẹẹ ni obinrin naa wi, lati tako fidio kan to ṣafihan baba oloogbe, nibi to ti n sunkun to si n pariwo niwaju ile Oba Edu.

Ta a ni Destiny Boy gan-an?

Afeez Adeshina gan-an ni orukọ rẹ, ṣugbọn Destiny Boy ni orukọ ti gbogbo eeyan mọ ọn si.

Ọmọ ilu Abeokuta ni, agbegbe Obantoko ni wọn ti bi i.

Destiny Boy pọ lọwọ iya rẹ, oun nikan ṣoṣo ni iya naa bi, koda, ọpọ eeyan maa n ro pe anti rẹ ni obinrin naa, nitori iya paapaa ko ti i fi bẹẹ dagba.

Baba rẹ bi awọn ọmọ miran ṣaa. Iya ati baba rẹ ko si fẹra wọn mọ tipẹ.

Bi ọjọ ori Destiny Boy ṣe kere to, oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii lo ṣi ile tuntun to kọ.

Bẹẹ ni a gbọ pe mọto to n lo fẹre to aadọta miliọnu naira (50m).

Ọdun 2024 ni Oloogbe Destiny Boy di ọlọmọ laye, nigba ti ọmọbinrin ti wọn jọ n fẹra wọn bimọ fun un.

Koda, nigba ti yoo ni ki ọmọbinrin naa fẹ oun gẹgẹ bii ọkọ rẹ tootọ, oruka Dayamọndi ẹlẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni wọn lo fi fun un.

Awọn to sunmọ Destiny Boy sọ pe o maa n mu ọti pupọ, eyi ti ọpọ eeyan to fẹran rẹ maa n koro oju si, ti wọn si maa n kilọ fun un.

Musulumi ni Destiny Boy, bo ṣe jẹ onifaaji naa ni wọn tun ni o fẹran ẹsin, to si maa n sin Oluwa.

Bakan naa lo si tun ṣẹ Ifa pẹlu, Oba Edu Ifayomi naa ni wọn lo ṣẹ Ifa fun un.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ogun bẹrẹ iwadii lori iku Destiny Boy, mu afurasi kan

Ṣaa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe oun ti bẹrẹ iwadii lori iku to pa Destiny Boy.

Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Oluṣeyi Babaseyi fi sita nirọlẹ ojọ Aje lo ti fidi eyi mulẹ.

Babaseyi fi kun un pe awọn ti mu afurasi kan lori iku Destiny Boy

Bẹẹ lo ni ẹka to n ri si ipaniyan labẹle ti bẹrẹ iwadii kikun lori ọrọ yii.

Destiny Boy, ọmọdé olórin tó kú lẹ́ni ọdún 22, ohun tí a mọ́ rèé

Oloogbe Afeez Adeshina (Destiny Boy)

Oríṣun àwòrán, temilolasobola

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Afeez Adeshina (Destiny Boy)

Oni ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni gudugbẹ miran tun ja lagbo orin, nigba ti iroyin iku ọdọmọkunrin olorin AfroFuji kan, Afeez Adeshina tawọn eeyan mọ si Destiny Child, gbode kan.

Ni ti ọjọ ori, Destiny Boy ko ju ẹni ọdun mejilelogun (22) lọ bi akọsilẹ ṣe wi.

Bakan naa ni iroyin sọ pe oun nikan ṣoṣo naa ni ọmọ ti iya rẹ bi, baba rẹ lo bi awọn ọmọ miran.

Ọdun 2024 , ninu oṣu Kọkanla ni Oloogbe Destiny Boy naa di ọlọmọ laye, nigba ti ọmọbinrin ti wọn jọ n fẹra wọn bimọ fun un.

Koda, nigba ti yoo ni ki ọmọbinrin naa fẹ oun gẹgẹ bii ọkọ rẹ tootọ, oruka Dayamọndi ẹlẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni wọn lo fi fun un.

Ki lo pa Destiny Boy?

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, a ko le fidi ohun to pa Destiny Boy mulẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn iroyin kan kede pe ile Babalawo kan ni ọmọkunrin naa ku si, bẹẹ ni awọn kan sọ pe o pọ awọn nnkan kan lẹnu nigba to fẹẹ jade laye.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe ẹjẹ lo pọ titi to fi dagbere faye.

Gẹgẹ bi gbajumọ akọroyin ori ẹka Instagram to maa n tọpinpin, Temilola Sobola,to kede iku Destiny Boy loju opo rẹ ṣe kede, o ni:

"Akọrin Destiny Boy ti ku. Ki Oluwa tẹ ẹ si afẹrẹ ire."

Amọ Sobola naa ko sọ idi iku Destiny Boy, o wulẹ kede iku naa ni.

Ṣaa, wọn ti sinku Oloogbe akọrin AfroFuji naa nilana ẹsin Islam, bẹẹ ni ọpọ eeyan to mọ ọn ti wọn si fẹran rẹ ti bẹrẹ si i daro rẹ

Igbiyanju wa lati ba amugbalẹgbẹẹ Oloogbe Destiny Boy sọrọ ko kẹsẹ jari, nitori nọmba rẹ ko lọ.