Ààrẹ Yoweri Museveni jáwé olúborí fún sáà kéje nínú ìdìbò Uganda

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty images
Ajọ eleto idibo ilẹ Uganda ti kede Aarẹ Yoweri Museveni bii ẹni to jawe olubori ninu idibo si ipo aarẹ to waye l'Ọjọbọ.
Gẹgẹ bi ikede naa ṣe wi, ninu onka ibo 7,946,772 ti awọn araalu di, Museveni nikan ni ida 71.65%.
Museveni to ti wa nipo aarẹ lati odun 1986 n lọ fun saa keje bayii, yoo lo ọdun marun-un miran nipo naa gẹgẹ bi ofin orilẹede Uganda.
Alatako rẹ gboogi ti wọn jọ figa gbaga, Bobi Wine, ni wọn kede pe o pawọ le Museveni.
Ibo 24.72% ni wọn kede pe Bobi Wine, olorin to di oloṣelu ni ni tiẹ. Ibo rẹ jẹ ( 2,741,238).
Ni ti awọn oludije mẹfa yooku, awọn ni wọn pin perete to ṣẹku
Amọ Bobi Wine ti ṣapejuwe esi ibo naa bii awuruju to kun fun magomago, bo tilẹ jẹ pe ikọ alabojuto (African Union election observers), sọ pe awọn ko ri apẹẹrẹ magomago tabi èrú kankan ninu idibo naa.
Ni oju iwoye tirẹ, Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan to lewaju ikọ to n ṣabojuto ibo nilẹ Afirca yii , sọ fun awọn akọroyin pe o yẹ kijọba Uganda ṣiwọ ninu pipa ẹrọ intanẹẹti nigba ti idibo ba n sunmọ.
Bakan naa lo ni oun ko gba iroyin nipaijinigbe ati ti pe wọn fi ofin gbe awọn eeyan kan.
Jonathan sọ pe wọn fi ko ẹru si ọkan awọn eeyan ni.
Èèyàn méje kú - bó ṣe ń lọ lórí ètò ìdìbò sípò ààrẹ ní Uganda

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Uganda ti jiyàn ẹ̀sùn pé wọ́n ti jí olùdíje sípò ààrẹ níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà lọ́jọ́bọ̀ tó kójá, Bobi Wine gbé lọ.
Ní ọjọ́ Ẹtì ni ìbò kíkà ń tẹ̀síwájú lórílẹ̀ èdè náà pẹ̀lú bí kò ṣe ojú òpó ayélujára tó ń ṣiṣẹ́ sàn-án.
Ẹgbẹ́ òṣèlú Wine fẹ̀sùn kàn pé níṣe ni ọkọ̀ òfurufú kan balẹ̀ sí ilé Wine tó wà ní Kampala tí wọ́n sì gbe Bobi Wine lọ sí ibi tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀.
Ṣáájú ni ọmọ Wine, Solomon Kampala náà ti kọ́kọ́ fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ti mú àwọn òbí òun méjéèjì ṣùgbọ́n tó padà sọ pé bàbá òun móríbọ́, tí ìyá òun sì wà ní ìgbélé.
Láti ìgbà náà sì ni àwọn èèyàn ti ń bèèrè ibi tí olùdíje náà wà.
Àtẹ̀jáde tí olùdíje sípò ààrẹ náà fi sójú òpó Facebook ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta sọ pé níṣe ni nǹkan le fún àwọn nílé òun tó wà ní Magere bí àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ológun ṣe yí ilé náà ká.
Ó fẹ̀sùn kàn pé àwọn ọlọ́pàá náà pa gbogbo ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV tó wà nílé òun, tí ọkọ̀ òfurufú sì ń yí ilé òun ká.
Ó ní òun ríbi sá mọ́ wọn lọ́wọ́ àmọ́ tí ìyàwó àtàwọn ẹbí òun yòókù sì wà lábẹ́ àhámọ́ wón nílé èyí tó ṣokùnfà ìdí táwọn èèyàn fi ń gbe kiri pé wọ́n ti jí òun gbé.
Àmọ́ agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Kituuma Rusoke nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta sọ pé olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú National Unity Platform, NUP, Bobi Wine wà nílé rẹ̀ ní Kampala, pé àwọn ẹbí rẹ̀ ló ń gbé ìròyìn òfégè nípa rẹ̀.
Ó ní lóòótọ́ ni lílọ bíbọ̀ rẹ̀ jẹ́ ohun tí wọ́n ń ṣàmójútó nítorí ilé rẹ̀ wà lára àwọn ibi tí nǹkan ti lè dàrú ni.
Rusoke ní àwọn kò lè fààyè gba àwọn èèyàn láti kóra wọn jọ láti máa da ìlú láàmú.
"Gbogbo ìgbésẹ̀ wa kò ṣẹ̀yìn láti dènà àwọn èèyàn láti dá wàhálà sílẹ̀ tàbí da ètò ààbò láàmú."
Ìròyìn tó ń jáde láti ọwọ́ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdìbò Uganda sọ pé Ààrẹ Yoweri Museveni ló ń léwájú nínú èsì ìdìbò tí wọ́n tik à báyìí pẹ̀lú ìdá méjìlélọ́gọ́rin nígbà tí Wine ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú ìdá mẹ́rìnlélógún.
Wine sọ fún àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì pé wọn ò gbọdọ̀ tẹ̀lé àwọn èsì ìbò irọ́ tí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdìbò ń gbé jáde, pé àwón ìjọba ń jí ìbò. Kò fi ẹ̀rí kankan síta láti fi gbe lsùn náà lẹ́sẹ̀.
"Mo kọ èsì ìbò tí Byabakama ń kà. Yàtọ̀ sí jíjí ìbò, bí àwọn ológun ṣe gba àkóso ètò ìdìbò náà, tí wọ́n sì ń fi àwọn èèyàn wa sí àhámọ́ ti sọ èsì ìbò náà di òbe," Wine kọ sójú òpó Facebook rẹ̀.
Bákan náà ló ní òun bu ẹnu àtẹ́ lu bí wọ́n ṣe ń pa àwọn aráàlú tó gbìyànjú láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn tako èsì ìbò náà.
Ó wòye pé àwọn aráàlú lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn tako títẹ ẹ̀tọ́ wọn lójú mọ́lẹ̀ lójúnà àti yan ẹni tó wù wọ́n sórí ipò.
Ìròyìn ní kò dín ní èèyàn méje, tó jẹ́ àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ alátakò tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn ní Butambala lọ́jọ́bọ̀.
Wo gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò ìdìbò láàárín Museveni àti Boby wine láti yan ààrẹ Uganda

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oni Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni idibo n waye ni Uganda, titi kan ti ipo aarẹ.
Koda, idibo ọhun ti bẹrẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ nnkan eelo ti wọn nilo ni ko si nikalẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii, eyi to n fa ọwọ aago idibo naa sẹyin.
Wọn ni ẹrọ ti wọn nilo lati fi ṣe idanimọ (Biometric identification kits)lo n fa, awọn kan si sọ pe oju opo ayelujara ti ko ṣiṣẹ ni.
Oludije mẹjọ lo n dupo aarẹ, bo tilẹ jẹ pe meji gboogi lo foju han ju, awọn naa ni Aarẹ Yoweri Museveni to ti wa nipo aarẹ Uganda lati 1986, to si fẹẹ lọ fun saa keje, ati Boby Wine, olorin to pada waa di oloṣelu.
Ẹni ọdun mọkanlelọgọrin (81) ni Aarẹ Museveni, nigba ti Boby Wine jẹ ẹni ọdun mẹtalelogoji (43).
Bi Museveni ṣe n sọ pe oun ko dagba lati ma dije, bẹẹ ni Boby Wine naa n leri pe oun yoo yi ijọba atijọ pada, oun yoo ṣe nnkan tuntun bii ọdọ, bi awọn eeyan Uganda ba fi ibo gbe oun wọle sipo aarẹ.
Ko si aaye pupọ fun awọn alatako ijọba ni Uganda, lara ohun ti wọn n koju ni atimọle, ati ki ọlọpaa maa da ipejọ wọn ru.
Bakan naa ni airiṣẹ ṣe pọ laaarin awọn ọdọ lorilẹede naa, bẹẹ si ni ọdọ lo pọ ju nibẹ, awọn ti ọjọ ori wọn ko ti i pe ọgbọn (30).
Lonii ọjọ idibo, aago meje aarọ ni wọn kede pe idibo yoo bẹrẹ, yoo si pari ni aago mẹrin.
Ìbò wo gan-an ni wọn n di ni Uganda?

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Eeyan to to 21.6 million lo fi orukọ silẹ lati dibo lonii ni Uganda, gẹgẹ bi akọsilẹ wọn ṣe wi.
Ipele mẹta ni idibo naa:
*Ibo aarẹ - Oludije mẹjọ lo wa fun ipo yii.
*Ibo ile igbimọ (1) - ẹkun idibo 353 lo wa lati ṣoju ninu idibo ile igbimọ aṣofin akọkọ.
*Ibo ile igbimọ (2) – obinrin 146 lo wa fun ipo aṣoju, ẹnikan fun ẹkun kan ni wọn yoo dibo yan.
Ta lo ṣee ṣe ko di aarẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yoweri Museveni(NRM)
Gẹgẹ bi a ṣe wi, Aarẹ Museveni ati Bobi Wine ni oludije gboogi ti ipo aarẹ naa foju han pe yoo ja mọ lọwọ ninu awọn ọkunrin mẹjọ to n du ipo naa.
Eyi ni igba keji ti Museveni ati Boby Wine yoo jọ dije, Museveni lo pada di aarẹ ni 2021, eyi ti ọpọ araalu sọ pe magomago pọ ninu ibo naa.
Ibo ida 58% ni wọn ni Aarẹ Museveni ni nigba naa, nigba ti Bobi Wine ni 35%.
Ẹgbẹ National Resistance Movement (NRM) ni Aarẹ Yoweri Museveni n ṣe. Bo si tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo fẹran rẹ nigba to kọkọ fipa gbajọba logoji ọdun sẹyin, kaluku lo ti n sọ bayii pe agidi ati ipa ni aarẹ agbalagba naa fi n ṣejọba Uganda.
Awọn awoye sọ pe Museveni ko fẹ kuro nipo naa mọ, wọn lo ti fẹẹ sọ ọ di ogun ibi rẹ, pẹlu bo ṣe jẹ pe oun yii naa ni aarẹ ti ọpọ ọmọ Uganda gbọnju ba .
Lọwọlọwọ yii, Aarẹ Museveni ni aarẹ kẹta to pẹ ju lori ipo ni Africa.
O ti ṣe atunṣe ofin orilẹeed naa, o yọ gbedeke ọjọ ori kuro fun oludupo aarẹ, eyi to fun un ni anfaani lati maa dije funpo naa lọ.
Awijare rẹ ni pe oun nikan loun le fi ọwọ ilọsiwaju ati alaafia ilu sọya.
Bobi Wine - National Unity Platform (NUP)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oludije keji to n tan kan-n-gbọn ju pẹlu Museveni ni Bobi Wine, ẹni ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Robert Kyagulanyi.
Lasiko kan, awọn eeyan Uganda fun un ni inagije ''Ghetto president", iyẹn Aarẹ agbegbe awọn eeyan ti ko ni nnkan kan.
Wọn ri I bii ọdọ to ni afojusun awọn nnkan to le mu ayipada rere ba Uganda.
Nnkan bii ọdun marun-un sẹyin ni Bobi Wine di gbajumọ to mu oṣelu lọkunkundun, ipo keji lo ṣe nigba to dije nigba naa .
Nigba naa si ni ẹgbẹ rẹ ti i ṣe NUP di ẹgbẹ alatako to pọju nile igbimọ.
Bi awọn eeyan Uganda ba tẹle ifẹ ọkan wọn lori ayipada, awọn awoye sọ pe o ṣee ṣe ko fi sọdọ Boby Wine.
Awọn oludije yooku ni: Frank Bulira, Robert Kasibante, Joseph Mabirizi, Nandala Mafabi, Mugisha Muntu and Mubarak Munyagwa.
Njẹ ibo yii ko ni I kun fun èrú?
Lọpọ igba ni ọpọ eeyan ti maa n bu ẹnu atẹ lu ilana idibo ni Uganda.
Ṣugbọn lọtẹ yii, awọn alabojuto sọ pe ibo naa yoo lọ ni irọwọrọsẹ, amọ awọn akọṣẹmṣẹ lati ajọ UN kilọ pe o ṣee ṣe ko jẹ bakan naa ni ọmọ yoo tun ṣe ori ninu ibo oni.
Lasiko ipolongo ibo, awọn alatako koju oriṣiriṣi idaamu, gẹgẹ bi awọn awoye ṣe tọka.
Awọn agbofinro da ipolongo Bobi Wine ru, wọn ko si fọwọ kan awọn ti Museveni.
Bakan naa ni ajọ alaanu, Amnesty International, ṣapejuwe bi wọn ṣe lo ẹrọ tajutaju, ata ati bi wọn ṣe fẹrẹ lu awọn kan pa lasiko ipolongo ibo bii iwa ọdaju ati ika.
Amọ ijọba Museveni sọ pe o yẹ ko ri bẹẹ lati ri I pe ibo alaafia ni awọn eeyan di.
Wọn ni ki awọn le dena rogbodiyan kankan to ba fẹ waye lọjọ ibo ni.
Bobi Wine ni tiẹ rọ awọn oludibo lati duro ti ibo wọn bi wọn ba di I tan, lati da aabo bo o, ko ma baa si magomago kankan.
Ṣugbọn awọn ajọ eleto idibo sọ pe ki kaluku gba ile rẹ lọ jẹẹ to ba ti dibo tan ni.
Wọn ni akoyawọ ni awọn yoo fi ka ibo naa, awọn olootu idibo ati awọn akọroyin yoo si boju to o bawọn ba n ka a.
Awọn awoye kan ti ni awọn ko gbagbọ ninu ajọ eleto Uganda ṣaa.
Bẹẹ ni awọn NUP naa sọ pe awọn ni ẹrọ kan to le mojuto ibo naa, ti ko ni i si ogun magomago, wọn ni oju opo Bluetooth ni ẹka imọ ẹrọ naa n lo.
Nipa igba ti esi idibo yoo de, ọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni won kede pe esi idibo naa yoo jade fun araalu lati mọ.
Eyi ri bẹẹ nitori wakati mejidinlaadọta (ọjọ meji) lẹyin idibo ni ofin sọ pe awọn ajọ eleto idibo gbọdọ kede esi idibo ti wọn ba di ni Uganda.
Iṣoro Uganda
Ọrọ nipa ọrọ aje jẹ ọkan lara idaamu to n koju orilẹede Uganda, paapaa julọ, airiṣẹ ṣe.
Owo to n wọle fun araalu kere, bo tilẹ jẹ pe o ti n gbera sọ lẹyin ajakalẹ arun Corona to waye lọdun mẹfa sẹyin, ṣugbọn iṣẹ ko ti I pọ to fun awọn ọdọ lati ṣe.
Ai si nnkan amayedẹrun tun kun iṣoro ilu naa, bẹẹ ni eto ẹkọ ati ti ilera mẹhe.
Ajẹbanu ni iṣoro miran ti Uganda tun n koju, ipo ogoje (140) ni wọn wa ninu aadọsan (180) ninu awọn orilẹede ti ajẹbanu wọ lẹwu, gẹgẹ bi akọsilẹ 'Transparency International annual Corruption Perceptions Index.
Gbigba owo ẹ̀yìn ati pinpin ẹtọ araalu yooku fun awọn to wa nipo ijọba tun kun iṣoro ti akọsilẹ wa fun ni Uganda.
BBC News Yoruba yoo maa fi to yin leti bo ba ṣe n lọ ninu idibo Uganda.


























