Ipa wo ni ogun Amẹrika àti Israel sí Iran yóò ní lára Naijiiria?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti Amẹrika ati Israel bẹrẹ si n kogun ja Iran, oniruru nnkan lo ti n ṣẹlẹ.
Bi Amẹrika ṣe kọlu Iran naa ni Iran n kọlu awọn orilẹede Arab to sunmọ latari ajọṣepọ wọn pẹlu Amẹrika.
Lara awọn orilẹede ti Iran ti kọlu lati gbẹsan lara Amẹrika ni Bahrain, UAE, Saudi Arabia, Oman ati Qatar.
Bi awọn eeyan ṣe n ku ni Iran naa lawọn eeyan ko le rinrinajo kuro lawọn orilẹede Arab ti Iran n ju ado oloro si.
Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ lo gbagbọ pe ogun yii ko kan awọn eeyan Afrika gbọngbọn, pupọ lara awọn ọmọ ilẹ Afrika to wa lawọn ilẹ ti ogun naa kan ni wọn ti n ha sọhun bayii.
Yatọ si awọn to ha sọhun, o jọ bii ipa ti ogun naa ni lori ọrọ epo rọbi ọrọ aje lagbaye ti n fẹ de Naijiria.
Ti ẹ ko ba gbabe, nnkan bii ọjọ meji sẹyin ni ileeṣẹ ifọpo Dangote fi kun owo epo ni Naijiria.
Ipa ti ogun Iran yoo ni lara owo epo ni Naijiria
Onimọ nipa ohun amuṣagbara ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Abuja, Ọmọwe Chukwemeka Ifegwu Eke sọ pe owo epo bẹntiro ni Naijiria ṣeeṣe ko le ni ẹgbẹrun kan naira ti ogun ọhun ba falẹ ju bo ṣe yẹ lọ.
Nigba to n sọrọ lasiko ifọrọwerọ kan lori ileeṣẹ iroyin NTA, o ni oun gbagbọ pe owo ti yoo naa le ma pọ ju bo ṣe yẹ lọ ti ogun naa ko ba kọja ọsẹ kan lọ.
O ni "Ti ogun naa ba le tẹsiwaju di oṣu kan tabi ko le oṣu kan, awọn to n ṣakoso owo epo lagbaye le ṣagbeyẹwo iye ti wọn n ta a.
"Ni Naijiria nibi, ẹ maa mura pe owo epo yoo le si… ko si ọgbọn ti a le da, ko iwa ti a le wu ki owo epo ma le si."
Akoba mii ti oogun naa le ṣe fun Naijiria
Onimọ miran, Ọmọwe Muda Yusuf, to jẹ adari ajọ to n ṣatilẹyin fun awọn olokowo aladani, CPPE, ni oniruru ọna ni ogun naa fi le ṣakoba fun Naijiria.
Ọmọwe ọhun ṣalaye pe yoo ṣakoba fun owo epo bentiro, owo epo disu ati owo epo ọkọ ofurufu.
Yusuf sọ pe ogun naa yoo fun ṣakọba fun karakata "stocks" Naijiria.
Elo lo ṣeeṣe ki a maa ra epo ni Naijiria nitori ogun Iran?
Ninu ero rẹ, o ni owo naa yoo le si latari pe ileeṣẹ ifọpo Dangote naa n ko epo rọbi lati ilẹ okeere wọle si Naijiria ni, owo dọla ilẹ Amẹrika lo si fi n ra epo ọhun lagbaye.
Nigba to n sọrọ lori ohun ti ijọba le ṣe ki ogun Iran ma ba pa ọmọ Naijiria lara pupọ ju, o ni lara nnkan ti wọn le ṣe ni ki wọn pese awọn ọkọ igboro ti kii lo epo bẹntiro.
Amọ o ni o ṣeeṣe ki owo lita epo bẹntiro kan to N1,050 latari ogun naa.
O ṣalaye pe eyii ko ṣẹyin bi ileeṣẹ ifọpo Dangote ṣe n ko lara epo to n fọ wọle si Naijiria lati ilẹ okere, orilẹede Iran si jẹ ọkan gboogi lara awọn orilẹede to ni epo bẹntiro julọ lagbaye.
Ti ẹ ko ba gbabe, yatọ si Iran ti Amẹrika n kọlu, awọn orilẹede ti iran n kọlu bii UAE ati Kuwait naa wa lara awọn orilẹede to ni epo julọ lagbaye



























