Èèmọ̀ ńlá ! Suleiman pa ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nílùú Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí, Ó ní torípé ó yìnbọn fún òun lójú àlá

Aworan afurasi kan ninu ahamọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ arakunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan ti orukọ rẹ n jẹ Lateef Suleiman to fi okuta fọ ori ẹgbọn rẹ pa lori ẹsun pe oun rii to yinbọn fun oun loju ala.

Gẹgẹbi awọn olopaa ṣe sọ, bi afurasi naa ṣe taji loju orun to ni oun ti la ala naa ni agboole Alegunlode ni ilu Sẹpẹtẹri ni ipinlẹ Ọyọ, kaka ko mu ọkan kuro lori ala naa, ọdọ ẹgbọn rẹ, Mustapha Amidu ẹni ọdun mejilelaadọta lo gba lọ, o gbe okuta nla kan o si fọ ọ mọ ẹgbọn rẹ ọhun lori ko to fi ẹsẹ fẹẹ.

Awọn ara adugbo gbiyanju ati doola ẹmi arakunrin naa, wọn gbe e lọ si ile iwosan aladani kan ti orukọ rẹ n jẹ Ileri Oluwa Hospital nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe arakunrin naa ti jade laye.

Bawo lọwọ olopaa ṣe tẹ afurasi naa kẹyin to salọ?

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ DSP Ayanlade Ọlayinka ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Badmus Yinusa ti oun pẹlu jẹ ọmọ agboole Alegunlode yii kan naa nilu Sẹpẹtẹri lo fi ọrọ naa to ọlọpaa leti ki awọn ọtẹlẹmuyẹ to fọn si igboro lati tọ ipasẹ afurasi ọdaran naa ki wọn to mu u.