Iran gbìyànjú láti ṣekúpa Trump - Iléeṣẹ́ ológun US

Oríṣun àwòrán, The White House via X Account/Anadolu via Getty Images
Ileeṣẹ ologun US ti kede pe awọn ṣekupa agbebọn kan lati orilẹede Iran ti wọn ni o gbiyanju lati ṣekupa Aarẹ Donald Trump.
Akọwe agba fun ileeṣẹ ologun, Pete Hagseth lo kede eyii.
O ni, "Iran gbiyanju lati ṣekupa Aarẹ Trump. Aarẹ Trump lo rẹrin ikẹyin".
Ọjọ Isẹgun ni wọn ṣawari olori ikọ agbebọn ti wọn gbiyanju lati ṣekupa Aarẹ Trump.
Ṣugbọn o kọ lati darukọ eeyan sita fun ara aye.
Ẹwẹ, lọdun 2024, ijọba Amẹrika fẹsun ọmọ orilẹede Afghan kan ti wọn ni o lẹ dipupọ pẹlu orilẹede Iran lati ṣekupa Trump, ko to di pe o bori eto idibo to gbe wọle.
Ẹka idajọ fẹsun kan Farhad Shakeri, ẹni ọdun mọkanlelaadọta, pe wọn gbe iṣẹ fun pe ko ṣekupa Trump
Ijọba Amẹrika kede lasiko naa pe awọn gbagbọ pe Shakeri wa ni orilẹede Iran.
Bawo ni ibọn ṣe ba Trump lọdun 2024?
Àwọn oṣojúmikoro to ba BBC sọ̀rọ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà daba wípé ìró ìbọn yẹn wá láti ilé alájà kan tó wà ní ọwọ otun sì ibi pátákò tí Trump tí ń sọ̀rọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà to ṣẹ.
Ọkàn nínú wọn, Greg, so fún BBC wípé óun rí arákùnrin tí ó ń faya wọlẹ lórí òrùlé ilé alájà kan náà ni bí ìṣẹ́jú marun sì asiko ti Trump bo si ori pátákò láti sọ̀rọ̀. Ó nipe òun tọ́ka ẹni tí òun fura si yii fún àwọn ọlọ́pàá.
"ìbọn wá ní ọwọ rẹ. Ó hàn dájúdájú wípé arákùnrin náà mú ìbọn lọ́wọ́. Àá ń tọ́ka ẹ fun àwọn ọlọ́pàá àmọ́ ṣe ni wọn ń sáré kiri lórí ilẹ̀. A sì ń sọ fún wọn wípé arákùnrin naa wà lórí òrùlé pẹ̀lú ìbọn àmọ́ nkan tó ń ṣẹlẹ̀ kò yẹ àwọn ọlọ́pàá," Greg ṣàlàyé.
Oṣojúmikoro miran, Jason sọ fún BBC wípé óun gbó ìró ìbọn ni igba marun un.
"A rí wọn ẹṣọ ààbò tí wọn bẹ mọ Trump láti dáàbò bo ó. Gbogbo èèyàn tó wà lójú agbo náà bẹ̀rẹ̀ ni kíákíá.























