Iná tó jó èèyàn mẹ́ta pa n'Ilorin, ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé

Aworan ṣọọbu ti ina ti ṣẹyọ
Àkọlé àwòrán, Aworan ṣọọbu ti ina ti ṣẹyọ naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ohun ibanujẹ gba lo jẹ ni ilu Ilorin to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara lọjọ kẹtadinlogun, osu kinni ọdun yii, latari bi awọn kan se jona mọ sọọbu ti wọn si dagbere faye, ti awọn mi-in si tun farapa kọja sisọ.

BBC News Yoruba sabẹwo si ile naa lati se iwadii lori ohun to sẹlẹ.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Aworan to ṣafihan ẹyin ijamba ina naa.

Awọn o soju mi koro ti wọn bẹbẹ ki a ma gbe orukọ wọn sita sọ pe ina naa bẹrẹ ni nnkan bi aago mẹfa irọlẹ, o si jo fun bi wakati kan abọ si wakati meji.

Wọn ní gbogbo igbiyanju awọn lati doola awọn ti wọn wa ninu ina lo ja si pabo.

Wọn sọ pe, "iya kan ti ọpọ eeyan mọ si iya Isila lo ni sọọbu to jo, awọn ohun ti iya naa n ta si jẹ epo kerosinni, epo bentiroolu, epo disu (diesel), enjin oili ati awọn ohun elo miran bẹẹ.

"O ti n sisẹ naa ti pẹ, alẹ nigba ti awọn ile epo ba ti lọ sun ni o maa n ta epo tirẹ ni fun awọn ọlọkada ati awọn onimoto ti wọn ba nilo rẹ.

"O sẹlẹ wi pe, iya yi sẹsẹ ja epo si sọọbu ni ki iṣẹlẹ ọun to sẹlẹ.

"Lọjọ buruku esu gbominu yii, iya Isila ko si nile, sugbọn akọbi ọmọ rẹ ti n se Islamiya Abdulwahab, ọmọ ọdun mejidinlogun ati awọn ọmọsẹ rẹ wa ni sọọbu.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ọrẹ Islamiya naa ti o n kiri bẹskẹ ati ọmọ ọdun mẹjọ kan to jẹ ọmọ fun asobata ẹgbẹ sọọbu naa wa ni bẹ.

"Gbogbo wọn si n wo fiimu lori foonu Islamiya, wọn si tun n bara wọn sere.

"Bi wọn ṣe n se eyi ni wọn n ṣe ounjẹ lori eedu ni faranda sọọbu naa.

"Bi eedu naa se kẹ laarin kan ni ina sọ ninu sọọbu, o si bẹrẹ si n jo awọn eeyan ati dukia nibẹ.

"Gbogbo awọn eniyan to wa nibẹ ni wọn gbiyanju sugbọn ẹpa o boro mọ,

"Bi awọn kan se n da yẹpẹ ni awọn kan n da okuta, bẹẹ si ni awọn mii n da omi.

"Gbogbo igbiyanju lo jasi pabo nitori ina naa pọ to jẹ pe, ko si ẹni ti o le sun mọbẹ, ati okere ni a ti n gbiyanju.

"Awọn to wa ninu ina naa n gbiyanju lati si ilẹkun onirin ti faranda naa sugbọn okunkun, eefin ati ina naa ko gba wọn laye lati farabalẹ ṣi i.

"Igba ti ina naa walẹ la ri i pe awọn eeyan yii ti ku lẹsẹkẹsẹ, awọn yooku to wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun naa ni wọn ti gbe lọ ile iwosan fun itọju.''

Iwadii fihan pe laarọ ọjọ Aiku ni wọn wa gbe awọn oku naa lọ si itẹ Musulumi to wa lagbegbe Oko-Olowo, lati fi ara wọn fun ilẹ.

Ìyá ló gbé bẹtiróòlù sí ṣọ́ọ̀bù ní Kwara tí iná fi jó ọmọ mẹ́ta pa-Iléeṣẹ panápaná

Aworan panapana to gbe ọpa omi dani, pẹlu awọn ero to n woran nibi ti eefin ina ti n ṣẹyọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara ti ṣalaye ohun to fa ina to jo awọn ọmọ mẹta kan pa nile kan lagbegbe Laduba, Ogidi, niluu Ilorin, lọjọ Satide ana ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Alukoro ati olori ẹka ikede nileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, PFO Hassan Hakeem Adekunle, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, pe nnkan bii yara marun-un, ṣọọbu mẹfa lo wa ninu ile naa.

O ni ṣọọbu mẹta to wa nisalẹ ile yii ni ina ọhun kan. Ati pe ina to ṣẹyọ naa ko ṣẹyin epo bẹtiroolu ti iya kan gbe sinu ṣọọbu tawọn ọmọ sun si.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Nigba to n ṣalaye bi ina ọhun ṣe ṣẹyọ gan-an, Alukoro ileeṣẹ panapana Kwara sọ pe iwadii fi han pe obinrin kan to ni ọmọ mẹta lo ra epo bẹtiroolu to to lita aadọta (50 litres) to si gbe e pamọ sinu ṣọọbu tawọn ọmọ sun si.

"Niwaju ṣọọbu naa, obinrin miran n dana eedu, bi eedu naa ṣe n kẹ lo ta de ibi ti wọn gbe epo bẹtiroolu pamọ si, eyi to mu ina ṣẹyọ to si pada gbina, to fa ijamba ina naa.

"Ina yii lo gba ẹmi awọn ọmọde mẹta, ti ẹnikan to n kọja lọ to si fẹẹ ran wọn lọwọ naa tun fi ara kona, to balẹ sile iwosan ki panapana too de."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade awọn panapana Kwara naa ṣalaye.

Wọn fi kun un pe olori agbegbe ọhun ni awọn gbe oku awọn ọmọde to di oloogbe naa fun.

Orúkọ àti ọjọ́ orí àwọn ọmọ tíná jó pa

Gẹgẹ bi ileeṣẹ panapana Kwara ṣe darukọ ati ọjọ ori awọn ọmọ naa, ẹni akọkọ ni

Abdulraman Jamiu Jeje, ọmọ ọdun mẹjọ.

Ikeji ni Islamiya Abdulwahab, ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) iya rẹ lo ni ṣọọbu.

Ẹnikẹta si ni Hadizah AbdulAzeez Raji, ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17).

Ọga agba nileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara CFS Alabi Muhammed, ba awọn ti iṣẹlẹ naa kan kẹdun, bẹẹ lo ni ijamba to ṣee dena ni.

O kilọ fun araalu lati yee tọju epo sile tabi ohunkohun to ba le gbina, paapaa lawọn ibi ti wọn ba ti n ta ọja, ti ina dida ko si jinna rara.

Bi wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni to n tọju epo sinu ile gbigbe, tabi to n huwa to le fa ijamba, olori ileeṣẹ panapana Kwara rọ awọn araalu lati tete fi ẹjọ ẹni bẹẹ sun, lati dena ijamba iru eyi lọjọ iwaju.