Ìmáàmù Ilorin wọ káà ilẹ̀, inú yàrá ìgbàlejò rẹ̀ ni wọ́n sin ín sí

Oloogbe Sheikh Muhammad Bashir Solih (Imaamu agba Ilorin nigba aye rẹ ati aworan sààréè rẹ ti wọn gbe sinu yara igbalejo rẹ. Awọn to n ṣeto naa wa nibẹ pẹlu.
Àkọlé àwòrán, Oloogbe Sheikh Muhammad Bashir Solih (Imaamu agba Ilorin nigba aye rẹ ati aworan sààréè rẹ ti wọn gbe sinu yara igbalejo rẹ. Awọn to n ṣeto naa wa nibẹ pẹlu.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Niṣe ni awọn eeyan lọ salalu bi iyanrin eti okun lasiko isinku Imaamu agba ilu Ilorin, Sheikh Muhammad Bashri Solih to jade laye lanaa ọjọ Aje, ti wọn si sin oku rẹ lonii ọjọ Iṣẹgun lagbegbe Egbejila, Ilorin.

Ohun to jẹ iyalẹnu ninu isinku naa ni pe inu yara igbalejo Imaamu agba Ilorin naa ni wọn sin oku rẹ si.

Laaarin ọgọọrọ ero ni wọn ti gbe oku Imaamu Bashir wọnu ile rẹ to wa ni ile kewu rẹ, (Muhammad Soliu Islamic Center, Egbejila, Ilorin), wọn si sin-in sinu yara igbalejo rẹ.

Saaju ni ọpọ eeyan ti peju si Aafin Emir Ilorin, iyẹn Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari, lati se adua ikẹyin ati lati kirun si oku lara.

Imaamu Imale ilu Ilorin, Sheikh Abdullahi Abdulhameed, lo dari adua isinku naa.

Bi eto isinku naa ṣe waye

Aworan ero rẹpẹtẹ nibi isinku Imaamu agba Ilorin, Sheikh Bashir
Àkọlé àwòrán, Aworan ero rẹpẹtẹ nibi isinku Imaamu agba Ilorin, Sheikh Bashir
Lasiko ti wọn gbẹ saaree tan ninu yara igbalejo Imaamu agba Ilorin

Ni nnkan bii aago mejila ọsan ni wọn fi ilẹ bo Imaamu Bashir lasiri, lẹyin naa ni awọn eeyan si wa si eti iboji rẹ lati tọrọ aforiji fun un.

Ọgọọrọ awọn Mùsùlùmí lo kirun si Imaamu to di oloogbe naa lara ni Ààfin Emir Ilorin.

Nibi ti ero pọ de nibi isinku yii, niṣe ni awọn agbofinro gan-an n tiraka ki wọn too ri awọn ero naa dari.

Ọpọlọpọ awọn imaamu Ilorin, lati ilu Eko, Offa ati awọn ilu mi-in ni Naijiria lo peju pesẹ sibẹ lati sẹyẹ ikẹyin fun imaamu Bashir.

Lara wọn ni Mufti ilu Ilorin; Sheik Farooq Onikijipa, Imam agba ti ilu Offa; Sheik Muyideen Salman, Imam Imale; Sheik Abdulameed Abdullah, Imam Gambari; Al-Imam Suleiman Abdulaziz to fi mọ awọn Balogun ati awọn eeyan pataki ni Ilorin ati ni Naijiria lapapọ.

Ìmáàmù àgbà ilú Ilọrin,Muhammad Bashir, jáde láyé

Oloogbe Imaamu Muhammad Bashir ti ilu Ilorin to doloogbe

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Imaamu Muhammad Bashir

Imaamu agba ilu Ilọrin ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, Sheikh Muhammad Bashir, (OON) ti jade laye .

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ Ẹmir Ilọrin, Ọmọwe Abdulazeez Arowona to tufọ iku Imaamu agba naa ṣe wi, oni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kin-in-ni ọdun 2026 ni Sheikh agba ilu Ilọrin naa dagbere faye.

Ta a ni Imaamu agba ilu Ilorin, Muhammad Bashir to doloogbe?

Imaamu Bashir Mohammed (OON) ni wọn bi lọjọ keje, oṣu Keje ọdun 1951.

Ẹmir Ilọrin kẹsan, Shehu Zulukanaini Gambari Mohammed lo yan an sipo naa.

Lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹwaa ọdun 1983 ni wọn yan an sipo imamu agba gẹgẹ bi imamu agba kejila ilu Ilọrin.

Lọjọ Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila ọdun to kọja ni wọn sefilọlẹ iwe to sọ nipa itan igbesi aye rẹ.

Oloogbe kẹkọọ gboye imọ ijinlẹ nile ẹkọ giga fasiti ilu United Kingdom lọdun 2013.

Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Ọmọwe Goodluck Jonathan, lo fi àmì ẹyẹ Officer of Order of the Niger (OON) da lọla lọdun 2012.

Imaamu Bashir si lo ọdun mẹtalelogoji lori ipo imaam agba ilu Ilọrin.

Ẹmir mẹta ọtọọtọ lo ba sisẹ ni ilu Ilọrin.

O jẹ gbajumọ onimọ ẹṣin Islam lagbaye.

O jade laye loni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kinni ọdun 2026, lẹyin aisan ranpẹ.

Àdánù ńlá ni ikú Imaamu àgbà Ilorin jẹ́- Ẹmir Ilorin

Ninu ọrọ rẹ, Ẹmir Ilọrin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari, ni titi lae ni wọn yóò ma seranti oloogbe naa.

Atẹjade agbẹnusọ Ẹmir Ilọrin, Ọmọwe Abdulazeez Arowona, ṣalaye bi Ẹmir ṣe ni iku Imaamu agba naa ba oun lojiji.

Ẹmir Ilọrin ni adanu nla ni iku Imaamu Bashir jẹ fun Ilọrin ati ipinle Kwara lapapọ.

O juwe oloogbe bií ẹni to kun fun imọ ati iwa irẹlẹ.

Ẹmir ni imaamu agba naa jẹ olootọ ẹda to si ni kun fun imọ ati oye.