Ọmọ ọdún mẹ́fà ni ọ̀rẹ́ ìyá mi ti ń fi ìbálòpọ̀ lọ̀ mí - Dele Alli

Aworan Dele Alli

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbabọọlu ọmọ orilẹede Gẹẹsi, to tun n gba bọọlu jẹun ni ẹgbẹ agbabọọlu Everton, Dele Alli ni ọmọ ọdun mẹfa ni oun nigba tirẹ ia oun ti n fi ọrọ ibalopọ lọ oun.

Ninu ifọrọwerọ kan to se pẹlu agbabọọlu Gẹẹsi tẹlẹ Gary Neville, Dele salaye pe oun ti oun la kọja nigba ewe pọ tobẹ gẹ to jẹ pe o ni ipa ninu awọn kudiẹkudiẹ kan to pada wa n de ba oun nigba ti oun dagba.

O ni ọpẹlopẹ awọn idile kan to gba oun tọ nigba ti oun pe ọmọ dun mejila lo jẹ ki irinajo oun tun na taara diẹ.

Dele, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn bayii sọ pe ọsẹ mẹfa loun lo laipẹ yii ni ile wosan itọju awọn iwa baraku (Rehab) fun ayẹwo nitori aṣilo ogun orun ati awọn ipenija ti oun n la kọja.

Tani Dele Alli?

Ti a ba sọrọ nipa ọdọmọde agbabọọlu, Dele jẹ ọkan lara ikọ Gẹẹsi to de ipele to kangun si aṣekagba (Semi Final) nibi idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2018.

kan gboogi lara ikọ agbabọọlu Tottenham wọ ipele asekagba idije Champion League lọdun 2019 labẹ iṣakoso akọnimọọgba ikọ naa nigba naa, Pochentino.

Sugbọn nnkan lọ bo ti yẹ mọ fun Dele Alli. eleyi lo mu ko fi ikọ Spurs silẹ lọ si Everton, ki awọn pẹlu to ya ikọ Bekistas, lorilẹede Turkey fun saa bọọlu ọdun 2022.

Amọṣa kọọ naa lo ri fun un ki o to tun pada si ikọ Everton lẹyin to ṣeṣe.

Dele, ẹti ṣoju ikọ agbabọọlu orilẹede Gẹẹsi ni ifẹsẹwọnsẹ mẹtadinlogoji.

"Nigba ti mo de lati Turkey, mo ri pe mo nilo isẹ abẹ, ti ọpọlọ mi si nilo ayẹwo.

"Mo pinnu lati gba ile wosan to n tọju nnkan to n se mi lọ fun itọju.

"O da bi pe asiko ti to fun mi. Wọn ko le sọ fun mi lati ma lọ. Mo fẹ mọ nnkan to n ló, ki n si gbe igbesẹ fun ara mi tabi ki n ma se. Inu okunkun ni mo wa, o gbera le ohun ti yoo se ijamba fun mi.

"Mo wa ji lojojumọ, mo n gbogun ti nnkan ti o n se mi, mo n lọ fun igberadi, mo n rẹrin, lati fihan pe inu mi dun sugbọn ni inu mi, mo n padanu ọpọ nnkan, ti asiko si ti to fun mi lati se atunse"

Ki lo sẹlẹ si Dele ni kekere?

Dele ni ọpọlọpọ nnkan lo sẹlẹ si oun nigba ewe, ti ko ye oun, ti oun ko si ri ojutu rẹ sibẹ.

"Iya mi jẹ omuti. Wọn fi soko si ilẹ Adulawọ lati lọ gbe pẹlu Baba mi lati le kọgbọn, ki wọn dẹ tun da mi pada.

"Nigba ti mo wa lọmọdun meje, mo ti bẹrẹ si ni mu siga.

" ni ọdun mẹjọ, mo ti n lo ogun oloro."

O niere bọọlu loun fi bẹrẹ si nii paronu rẹ bi o tilẹ jẹ wi pe oun ṣi n lo ogun oloro labẹlẹ.

Dele Alli fi kun un pe, alasunkiri loun nigba ti oun wa ni nnkan bii ọmọ ọdun mọkanla, to si jẹpe abẹ afara loun n sun kiri.

"Nigba ti mo pe ọmọ ọdun mejila, awọn mọlẹbi kan gba i tọ, To ba jẹ pe Ọlọrun lo n sẹda eeyan, awọn ni Ọlọrun sẹda nitori gbogbo nnkan ti wọn se fun mi."

Dele sọrọ lori awọn iwa baraku to n ba finra

Alli fikun pe o lero pe bi oun se sọrọ sita yii oun yoo ran awọn eeyan miiran to n ba idojukọ bada ri iwosan.

O un lilọ ile wosan fun itọju se ọpọlọpọ anfani ati iwosan fun oun, ti oun yoo se pada si ere idaraya pada

"Lilọ ile wosan ba mi lẹru sugbọn n ko mọ nnkan ti ma ba pada ati awọn ti ma jẹ anfani.

"Ipo ti mo wa ko da rara, Ọpọlọpọ nnkan lo waye nigba ti mo wa kekere ti ko ye mi rara.

Alli se ikilọ pe ọpọlọpọ ijamba lo wa ninu lilo ogun oorun, ti awọn akẹgbẹ rẹ si pẹlu awọn to n lo awọn ogun naa.