Ìjoba Amẹrika kéde orúkọ àwọn ológun rẹ̀ tó ti bá ogun Iran lọ báyìí
Oríṣun àwòrán, US Army Reserve Command
Ijọba ilẹ Amẹrika ti kede orukọ awọn ọmọ ogun rẹ to kọkọ ba ogun ti oun ati Israel n gbe ti iran lọ.
Ọmọ ogun mẹfa lo jade laye lẹyin ti ado oloro kan ja lulẹ si ojuko ọmọ ogun Amẹrika to wa ni Port Shuaiba, lorilẹede Kuwait, lọjọ Aiku.
Ajọ to n ri si ọrọ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika, US Central Command kọkọ sọ pe ọmọ ogun mẹta lo ku ninu ikọlu naa amọ awọn alaṣẹ pada sọ lọjọ Aje pe awọn mẹta mii tun ku lẹyin ti ẹnikan gbẹmi mi latari ọgbe to gba, ti wọn tun ri oku eeyan meji mii labẹ nnkan to dawo.
Orukọ mẹrin lara awọn oloogbe naa ni Capt Cody Khork, ẹni ọdun marundinlogoji, Sgt Noah Tietjens, ẹni ọdun mejilelogoji, Sgt Nicole Amor, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ati Sgt Declan Coady, to jẹ ẹni ogun ọdun pere.
Khork, to jẹ olugbe ilu Florida lo ti kọkọ ṣiṣẹ ni Saudi Arabia, Guantanamo Bay ati Poland.
Amor to wa lati Minnesota ti kọkọ ṣiṣẹ ni Kuwait ati Iraq.
Tietjens, to wa lati Nebraska ti ṣiṣẹ nigba meji ọtọto ni Kuwait ṣaaju iku rẹ.
Nibi ipade kan lọjọ Aje, minisita eto abo, Pete Hegseth sọ pe ohun ija oloro nla kan lo kọlu ibi ti awọn ologun naa wa.
Ileeṣẹ iroyin CBS sọ fun BBC pe inu ọọfisi kekere kan lawọn ọmọ ogun naa ti n ṣiṣẹ ki ikọlu ọhun to waye.
Ẹwẹ, ibaṣepo to dan mọran lo wa laarin ijọba Amẹrika ati Kuwait, nnkan bii ẹgbẹrun mẹtala ọmọ ogun Amẹrika lo si wa ni bẹ.
Lẹyin ti Amẹrika ati Israel bẹrẹ ikọlu si Iran naa ni Iran naa bẹrẹ si n kọlu awọn orilẹede to n ba Amẹrika dọrẹ.
Lara awọn orilẹede ti Iran ti kọlu lati gbẹsan lara Amẹrika ni Bahrain, UAE, Saudi Arabia, Oman ati Qatar.
Awọn fidio ti a ri ṣafihan baalu ologun Amẹrika to ja lati oju orufuru si ilẹ amọ awọn to n tukọ rẹ tete fo jade ninu rẹ ko to de ilẹ.
Ijọba Iran ni oun loun ja awọn baalu ologun naa bọ lati oju ofurufu amọ ko fi ẹri kankan lelẹ pe oun lo ṣe bẹẹ ni tootọ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available