Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Eko fẹ́ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olórí agbègbè tí wọ́n wó ilé wọn ní Makoko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile igbimọ aṣofin Eko ti fiwe pe awọn olori agbegbe ti ijọba ipinlẹ yii ti wo awọn ile ni Makoko, ipinlẹ Eko.
Ọla ode yii ti i ṣe ọjọ kẹta, oṣu Keji ọdun 2026 ni ipade naa yoo waye laaarin awọn olori agbegbe ti ile wiwo naa kan ati ijọba.
Iwe ipe naa ti Akọwe ile igbimọ aṣofin Eko, Olalekan Onafeko kọ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii lo fidi ipade naa mulẹ.
Nipa ibi ti ipade naa yoo ti waye, gbọngan ti wọn n pe ni 'Chamber Conference Room', àjà keji, nile igbimọ aṣofin Eko ni Onafeko sọ pe yoo ti waye.
Aago mẹwaa owurọ ni yoo si waye gẹgẹ bi lẹta ipe naa ṣe sọ.
Ki lo mu ipade wa?
Tẹ o ba gbagbe, ijọba Eko wo awọn ile ni Makoko to jẹ agbegbe omi, pẹlu alaye pe pupọ ninu awọn ile naa lo wa nibi ewu to le mu ẹmi ọpọ eeyan lọ.
Wọn ni awọn ile miran wa labẹ waya ina to lagbara to si le gba ẹmi ọpọ eeyan.
Eyi ni ijọba Gomina Sanwo-Olu sọ pe oun fẹẹ dena, to fi wo awọn ile agbegbe omi naa, ti ọpọ eeyan to n gbe nibẹ si di alainile lori.
Awọn kan tilẹ ti sọ inu ọkọ oju omi di ibugbe wọn latari ile wọn ti ijọba wo naa.
Wọn ni ko si ibi ti awọn yoo ko lọ latari ai si owo tawọn yoo fi gba ile miran.
Ọrọ naa lo ti di ariwo latigba ti ijọba ti bẹrẹ igbesẹ ile wiwo yii, awọn eeyan ti ọrọ kan n fi ẹhonu han, bẹẹ ni ọpọ araalu ati awọn ajafẹtọọ ọmọniyan n sọ pe ijọba wulẹ fẹẹ gba Makoko lati sọ ibẹ di adugbo awọn olowo ti araalu lasan ko ni I le gbe mọ ni.
Lẹyin awuyewuye ti ko ti I duro naa ni awọn eeyan agbegbe yii gba ẹnu awọn olori wọn sọrọ, nipa kikọ lẹta ifisun sijọba, eyi ti wọn kọ lọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.
Abajade iwe ifisun naa si ni ipade ti ijọba pe si ile igbimọ aṣofin Eko naa.
Ninu lẹta ti Akọwe ile igbimọ naa fi pe awọn olori agbegbe ti ọrọ kan ni Makoko lo ti ni:
" A rọ yin pe ki ẹ wa si ipade yii pẹlu awọn olori agbegbe, ki ẹ si ko awọn iwe to ba yẹ dani, eyi ti yoo mu asoye waye."
Alaye awọn eeyan Makoko ni pe ijọba ti wo kọja ibi ti wọn ni awọn yoo wo, bẹẹ ni wọn ko ti I dawọ ile wiwo ọhun duro.
Yatọ si ile gbigbe, wọn ni ijọba tun wọ ile ẹkọ, awọn ile iwosan kereje ati awọn nnkan amayedẹrun ti awọn n dọgbọn lo lowo pọọku.
Eeyan marun-un ni wọn lo dagbere faye lasiko ti ile wiwo naa n lọ lọwọ, ninu eyi ti awọn ọmọde mẹta wa, latari ẹrọ tajutaju ti wọn lo mu ẹmi wọn lọ, ti awọn agba si ku nitori ẹjẹ riru to ti wa lara tẹlẹ.
Ibi ti a mọ si Makoko yii jẹ agbegbe odo/ irà to ti le ni ọgọrun-un ọdun.
Awọn ẹya Ogu (Ègùn) ati Ilaje lo si pọ nibẹ ju.
Iye ìgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti wó ilé aráàlú láàárín ọdún kan sẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn olugbe agbegbd Mokoko, nipinlẹ Eko ti gunle ifẹhonuhan lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa wo awọn ile wọn.
Nigba ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ, awọn eeyan naa sọ pe lati opin ọdun to kọja ni ijọba ipinlẹ naa ti bẹrẹ igbeseẹ lati sọ awọn di alanilelori.
Amọ ijọba ipinlẹ ọhun ti fesi pe igbesẹ wiwo awọn ile naa kii ṣe lati gbogun ti awọn alaini to n gbe ni Makoko, amọ o wa fun lati daabo do ẹmi ati dukia awọn olugbe agbegbe naa.
Ijọba sọ pe pupọ ninu awọn eeyan ọhun lo n gbe labẹ waya ina to lagbara, eyii tole gbẹmi wọn laipẹ ọjọ amọ ijọba ko fẹ ki irufẹ nnkan bẹẹ waye lo ṣe tete bẹrẹ si n wo awọn ile ọhun.
Wayi o, kii ṣe Makoko yii nikan ni ijọba ipinlẹ Eko ti n wo awọn ile lẹnu ọdun kan sẹyin, eyii to n bi awọn to n gbe lawọ ile naa ninu.
Iwọnyii lawọn agbegbe ti ijọba Eko ti wo ile laarin ọdun kan sẹyin.
Agbegbe Adeniji-Adele - Ọdun 2024 si 2025
Laarin oṣu Kọkanla ọdun 2025, si oṣu Kẹrin ọdun 2025 ni ijọba ipinlẹ Eko wo awọn ile kan lagbegbe Adeniji-Adele.
Ijọba sọ pe awọn ile ti ko gba ontẹ ijọba, to fi mọ awọn ile ti ko ba gba igba mu, eyii ti awọn ọmọ ota n gbe ni wọn wo.
Bẹẹ naa ni wọn tun wo awọn ile onipaanu ti awọn eeyan kan kọ si abẹ awọn afara, eyii ti awọn kọlọrọsi ẹda n gbe lasiko naa.
Ijọba tun ni oun wo awọn ile to n di oju agbara kọja.
Adeniji-Adele ati Ọja Ọba ni ọrọ naa kan gbọgbọn julọ
Oworonski - Ipari ọdun 2025
Ninu oṣu Kejila, ọdun 2025, ijọba ipinlẹ Eko wo awọn ile kan lagbege Oworonsoki, paapaa nibi to fẹgbẹkẹgbẹ afara Third Mainland.
Awọn eeyan to n gbe lagbegbe naa ṣaaju igbesẹ ọhun sọ fun awọn akọroyin pe ijọba ko bun awọn gbọ ko to bẹrẹ si n wo awọn ile naa.
Amọ awọn iwadii kan fi pe ijọba ti fi ikilọ sita ni nnkan bii ọdun kan ṣaaju igbesẹ naa pe ki awọn eeyan ọhun kuro nibẹ ko to bẹrẹ si n wo awọn ile naa.
Ọrọ naa le to bẹẹ ti awọn eeyan Oworonsoki bẹgi dina ori afara Third Mainland, eyii to mu nira ba awọn to n bọ lati Victoria Island lati kọja, o si mu inira ba ọpọ eeyan lọjọ naa lọhun ki ọlọpaa to fi gaasi tajutaju le awọn olufẹhonuhan naa.
Lara awọn ti ọrọ naa kan ni arabinrin Rebecca Omolayo ti wọn wo ile rẹ.
Obibrin naa sọ fun awọn akọroyin pe ko si ibi ti mọlẹbi oun le lọ ayafi ti ijọba ba ṣaanu awọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikota-Lekki
Ninu oṣu Karun, ọdun 2025, ijọba Eko wo awọn ile kan lagbegbe Lekki si Ikota.
Kọmiṣọna fun ọrọ ayika ati omi, ọgbẹni Tokunbo Wahab sọ fun awọn akọroyin lọdun naa pe eredi igbesẹ ọhun ko ṣẹyhin bi awọn eeyan kan ṣe kọ ile si agbegbe ti ọna ijoba gba kọja.
Lara awọn agbegbe ti ọrọ naa kan lasiko naa ni awọn ile to wa nileegbe Oral Extension Estate, Westend ati Megamound Estate.
Makoko - ọdun 2026
Ninu oṣu Kinni, ọdun 2025 yii ni ifẹhonuhan bẹ silẹ laarin awọn eeyan to n gbe Makoko lẹyhin ti awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko gbe ọkọ wa lati wa wo awọn ile nibẹ.
Iroyin ni nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọọdunrun eeyan to n gbe lagbegbe ọhun ni yoo padanu ile wọn latari igbesẹ naa.
Awọn eeyan ọhun fẹsun kan ijọba Eko pe o n wo ile awọn lai pese agbegbe mii fun awọn.



























