Ta ni Trump yóò fà kalẹ̀ láti ṣe igbákejì rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laarin ọjọ diẹ si asiko ti a wa yii, oludije sipo aarẹ ilẹ Amẹrika labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Republican, Donald Trump yoo kede ẹni to fẹẹ lo gẹgẹ bi igbakeji rẹ.
Nigba ti ipade gbogboogbo fẹgbẹ oṣelu Republican ba bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lọjọ Aje, ọsẹ to n bọ, gbogbo ireti ọjọ pipẹ awọn araalu yoo dopin, oludamọran pataki fun Trump, Jason Miller lo sọ eyi fun akọroyin ileeṣẹ FOX.
Trump funra rẹ naa sọ pe: “Maa fẹẹ ṣe e ni ti ọna atijọ, maa si ṣe e lasiko ipade gbogboogbo.”
Orukọ mẹta lo ti n kaakiri igboro nipa ẹni ti Trump yoo kede ninu wọn, ṣugbọn sibẹ, awọn miran tun ṣi wa nilẹ ti yoo jẹ iyalẹnu nla.
Bayii ni agbeyẹwo ọhun.
JD Vance

Oríṣun àwòrán, Reuters
JD Vance, ẹni ọdun mọkandinlogoji, sẹnetọ kekere lati Ohio ti ṣatilẹyin nipa ipolongo ita gbangba fun Trump lọpọ igba laarin awọn oṣu to kọja.
Akẹkọọ ile-ẹkọ Yale tẹlẹ naa to tun ti kọ ọkan lara awọn iwe to ta julọ Hillbilly Elegy, eyi to fi sọ itan aye rẹ lori bo ṣe bẹrẹ igbesi aye lati ibẹrẹpẹpẹ ni Midwest.
Vance to ti figba kan ri tako ipolongo Trump lo tun erongba rẹ pa lati jade fun ipo Sẹnetọ lọdun 2022, ti Trump naa si fontẹ lu.
Nigba to wa nipo, ọpọ ẹjọ lo ti ṣatilẹyin fun, eyi to nii ṣe pẹlu Trump, to si n duro digbi lati kin Trump lẹyin.
Ọgbẹni Vance gbagbọ pe oun yoo jẹ irinṣẹ gidi fun ijọba Trump lọjọ iwaju nile igbimọ aṣofin, bo tilẹ jẹ pe ko tii sọ pe oun ko nifẹ si ipo igbakeji-aarẹ.
“Mo fẹẹ ran an lọwọ gẹgẹ bi mo ṣe le ṣe,” o sọ eyi laipẹ.
Trump naa tun ti pana awuyewuye lo n lọ kaakiri igboro wi pe irungbọn ti Ọgbẹni Vance ni ko nii jẹ ki Trump lo o gẹgẹ bi igbakeji rẹ, pẹlu bi ko ṣe fẹran irungbọn.
Doug Burgum

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹlomiran toun naa tun fidi rẹmi nibi idibo abẹle to gbe Trump wọle ni Doug Burgum, ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin (67). Saa keji lo n ṣe lọwọ gẹgẹ bi gomina ipinlẹ North Dakota.
Ọgbẹni Burgum ko ipa rere diẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ, ṣugbọn to pada bẹrẹ atilẹyin fun Trump.
Lọdun 2023 ni Burgum sọ pe oun ko le ohunkohun lati ṣe papọ pẹlu Trump nitori pe ko ṣakoso ileeṣẹ rẹ daadaa bo ti tọ, ati bo ti yẹ.
Ọgbẹni Burgum bẹrẹ irin ajo rẹ nipa ṣiṣe awọn irinṣẹ igbalode (software), eyi ti ileeṣẹ Microsoft pada ra lọwọ ẹ, ati pe awọn okoowo to gbajumọ lati ibẹrẹ pẹpẹ lo sọ ọ di olowo yanturu.
A gbọ pe o ti wu Trump lori pẹlu awọn iwa awada rẹ ati ọrọ oṣelu, eyi to jẹ ki wọn yan igbakeji Mike Pence lọdun 2016.
Oyun ṣiṣẹ to ku diẹ ki wọn fofin de ni North Dakota, eyi ti Burgum ṣatilẹyin fun “tun jẹ eyi to fẹẹ da awuyewuye silẹ”, Trump sọ eyi nibi ifọrọwerọ to ṣe nileeṣẹ redio Fox.
“Mo lero pe eeyan nla Doug, ṣugbọn...o ti ko ipa to jọju to si duro digbi,” o sọ eyi
Burgum ti sọ pe oun yoo ṣatilẹyin fun fifi ofin de oyun ṣiṣẹ titi de ipinlẹ ẹnikọọkan, ẹgbẹ oṣelu Replubican si ti daba rẹ ninu agbekalẹ ẹgbẹ wọn lati fofin de oyun ṣiṣẹ.
Ọrọ oyun ṣiṣẹ yii lo tun jẹ ki awọn oludibo sare tẹle ẹgbẹ oṣelu Democratic nigba ti eto idibo de aarin meji lọdun 2022.
Marco Rubio

Oríṣun àwòrán, Reuters
Trump ati Marco Rubio ko gba ti ara wọn rara lasiko eto idibo abẹle ti ẹgbẹ oṣelu Republican lọdun 2016. Trump pe e ni "Little Marco" nitori bo ṣe ri, bẹẹ naa si ni Rubio maa n sọrọ lori ọwọ kekere ti Trump ni.
Sẹnetọ to n ṣoju Florida naa ti wa bẹrẹ sii ṣiṣẹ papọ pẹlu Trump, to si ti bẹrẹ atilẹyin fun un latigba ti eto idibo abẹle ti pari.
Lọdun 2012 ni wọn gbe Rubio dide gẹgẹ bi igbakeji FUN Mitt Romney.
Gẹgẹ bi ẹni ọdun mẹtalelaadọta, agbeyẹwo wa pe o o ṣi kere, to si tun ni ọkan akikanju lati ṣiṣẹ, ati pe yoo tun ṣanfaani fun Trump lati ri ibo ni Latino.
Rubio sọrọ nibi ipolongo kan to ṣe fun Trump ni Florida lọjọ Iṣẹgun kọja, bẹẹ si ni oludije sipo aarẹ naa sọ pe “Ọkunrin to dara ni... Marco jẹ alagbara ni alẹ ana, o si gbajumọ. O si tun jẹ ọkan lara awọn ti a n woye rẹ.”
Iwe ofin ilẹ Amẹrika le faaye silẹ fun ilana. O tọka si wi pe ipinlẹ yoo fun o kere julọ, oludije kan ṣoṣo, yala aarẹ tabi igbakeji rẹ ti wọn ko wa lati ipinlẹ kan. Ọgbẹni Rubio ati Trump ni wọn jọ n gbe ni Florida, eyi ṣee ṣe ko jẹ pe gbogbo ibo ọgbọn to wa ni ipinlẹ naa ni iyemeji wa lori ẹ.
Ni ojuṣe, wọn le yanju rẹ pẹlu ọpọ Republican to gba tikẹẹti, tabi ki ọkan lara awọn oludije naa kuro ni ipinlẹ ọhun.
Lọdun 2000, Dick Cheney gbe ile rẹ kuro ni Texas lọ si Wyoming, lati di igbakeji ọmọ Texas kan, George W Bush.
Trump ti wa sọ pe ko si wahala kankan pẹlu Ọgbẹni Rubio, “ṣugbọn yoo tun jẹ ki ọrọ ọhun peleke sii ni.”
Tim Scott

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lai si ariyanjiyan, Sẹnetọ Tim Scott ni eeyan dudu to gbajumọ julọ lorileede naa, o si wa lara awọn afigagbaga ti Trump fidi rẹ rẹmi ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu naa to kọja.
Ọgbẹni Scott, ẹni ọdun mejilelaadọta yan idanimọ rẹ nipa afojusun rẹ gẹgẹ bi ajihinrere to gbajumọ, to si fi ẹsin polongo ibo, ṣugbọn to pada ja kulẹ.
Lẹyin ilakaka lati ko owo jọ, nibi itakurọsọ ẹẹmẹta ọtọọtọ ti ko ti ṣe daadaa, o jawọ, o si tete fontẹ lu Trump lati ṣatilẹyin fun un.
Iṣẹlẹ to mu iwuri ati atẹwọ nla dani lo jẹ nibi ipolongo ibo fun Trump ko to di pe idibo abẹle New Hampshire to jẹ ko maa lewaju gẹgẹ bii olufigagbagba to ṣe daadaa julọ fun ipo igbakeji aarẹ.
“A nilo Donald Trump," o sọ eyi, ko to di pe o farahan lori itage nigba ti wọn dupẹ aṣeyọri.
O sọ fun Trump pe: “Mo ṣaa kan nifẹẹ rẹ.” Pẹlu ẹrin ni aarẹ tẹlẹri naa fi dahun pe: “Idi niyẹn ti o fi jẹ oloṣelu to dara.”
Latigba naa, ni Trump ti maa n sọ ọ ni gbogbo igba pe Scott ṣi “dara nipa pipolongongo fun mi ju bo ti n ṣe funra rẹ lọ.”
Byron Donalds

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹni ọdun marundinlaadọta ni Byron Donalds, to si ti ṣe iranwọ nipa jijẹ eeyan dudu to n ṣe daadaa, to si tun jẹ alakitiyan gidi.
Donalds ti iya rẹ da tọ ni wọn bi si New York, to si ṣiṣẹ lẹka ileeṣẹ eto ile ifowopamọ, fifi owo dokoowo ati eto iṣuna ko to di pe o darapọ mọ oṣelu ni Florida lọdun 2012.
Lẹyin ọdun mẹrin ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin ni Florida, o tun ti sin ilu lati ọdun 2020 nile aṣofin ilẹ Amẹrika, to si n ṣoju apa ọtun ti ẹgbẹ rẹ ni Washington.
Lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹfa, Ọgbẹni Donalds darapọ mọ Trump nibi ipolongo ibo to waye ni Michigan, pẹlu erongba lati fa ọkan awọn eeyan dudu mọra fun Trump.
Aarẹ tẹlẹri naa wa sọrọ nita gbangba wi pe Ọgbẹni Donalds yoo jẹ alakikanju igbakeji to ṣee mu yangan.
“Byron Donalds jẹ ọkunrin to dara, to si tun jẹ olotitọ, mo si woye pe yoo wa lara awọn igbakeji aarẹ ti yoo ṣe daadaa pẹlu ọkan akikanju. Ṣe ẹnikẹni ninu yin yoo nifẹẹ lati rii gẹgẹ bii igbakeji aarẹ?”
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti ileeṣẹ iroyin Fox, o sọrọ nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya oun pẹlu Trump ti jọ sọrọ lori iṣẹ naa.
“To ba ri bẹẹ, bi ko si ri bẹẹ...ṣugbọn maa fi iyẹn pamọ funra mi.” Ọgbẹni Donalds jẹ ko di mimọ.
“Mo lero wi pe Aarẹ Trump yo ṣe ipinu to dara,” o tẹsiwaju. “O daju pe ipinnu rẹ ni, ipinu adaṣe si ni.”
Elise Stefanik

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Elise Stefanik, ẹni ogoji ọdun to jẹ oloṣelubinrin lati New York, bẹẹ lo si tun jẹ obinrin to wa loke julọ ninu ẹgbẹ oṣelu Republican nile igbimọ aṣoju-ṣofin ilẹ Amẹrika.
Ọkan pataki tun ni Elise Stefanik jẹ ninu awọn ọmọ ẹyin to duro digbi ni Capitol Hill, koda, pẹlu wi pe o wa lara awọn to fẹẹ yọ Trump nipo lọdun 2020.
Lawọn ọdun diẹ sẹyin, o ti dide lati jẹ ẹni to n ṣe daadaa julọ ninu awọn iwe iroyin kaakiri.
Bẹẹ lo ti sọ ọ nita gbangba pe oun iwuri nla ni yoo jẹ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu Trump ninu iṣakoso rẹ ni eyikeyi ẹka, bo tilẹ jẹ pe ko si ninu awọn to wa loke nipa ifigagbaga lati jẹ igbakeji-aarẹ.
Tulsi Gabbard

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi oloṣelu Democrat, oun ni aṣoju awọn ẹya Hindu akọkọ nibi ipade gbogboogbo ilẹ Amẹrika. Ni bayii, Tulsi Gabbard le jẹ ẹni ti yoo lagbara julọ ninu iwe akọsilẹ Trump fun igbakeji.
Lọdun mẹwaa sẹyin, gbajugbaja ninu ogun ilẹ Iraq ati alakikanju ninu ọmọ ogun ilẹ Amẹrika, o ṣiṣẹ gẹgẹ bi igbakeji alaga-binrin fun igbimọ apapọ ti Democratic (DNC), ko to kọwe fipo silẹ lati gbaruku ti oludije sipo aarẹ lọdun 2016, Bernie Sanders.
Asiko rẹ nibi ipade gbogboogbo lọdun 2013 si 2021, lo kun fun atako si iṣakoso Ọbama ati bi ileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika ṣe n da si ọrọ.
Lọdun 2020 loun naa jade du ipo aarẹ, to si kopa nibi idibo abẹle, to si gbajumọ daadaa lati jẹ alagbeyẹwo si Kamala Harris - ẹni to ti wa jẹ igbakeji aarẹ - lori ipa to ko gẹgẹ bii onidajọ ni California.
Ms Gabbard, ẹni ọdun mẹtalelogoji naa sọrọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Fox lọdun 2022 wi pe oun ti n fi ẹgbẹ oṣelu Democratic silẹ. Ṣugbọn o ṣi tun le jẹ iyalẹnu bi wọn ba mu.
Kristi Noem

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kristi Noem, gomina South Dakota, ti figba kan leke nibi agbeyẹwo ti awọn alatilẹyin Trump gbe kalẹ lori taa ni yoo di igbakeji aarẹ.
Noem, ẹni ọdun mejilelaadọta naa lo dide si ipo gbajugbaju pẹlu bo ṣe n farahan lori iroyin Fox, paapaa julọ nigba to daba pe ki awọn eeyan maa lo iboju lasiko ajakalẹ arun to kọja.
Irawọ rẹ tun tan gidi titi digba to fi gbe apilẹkọ rẹ jade, nibi to ti ṣalaye bo ṣe yinbọn fun aja rẹ to le lọdun kan ati oṣu meji, nitori ti ko ṣe daadaa bo ṣe fẹ.
Iroyin naa gba igboro to mu ki awọn eeyan bẹrẹ sii bu atẹ luu kaakiri, ati pe sibẹ, o ṣi ninu awọn ti wọn n ṣagbeyẹwo rẹ fun ipo yoo.
Awọn orukọ miran to tun wa ninu agbeyẹwo
Ben Carson
Tom Cotton
Vivek Ramaswamy
Ron DeSantis
Nikki Haley
Katie Britt
Kari Lake
Sarah Huckabee Sanders
























