Super Eagles: Sunday Dare, mínísítà eré ìdarayá ní kò dájú pé Gernot Rohr kún ojú ìwọ̀n àti ṣàkóso Super Eagles

Awọn agbabọọlu Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Twitter/Sunday Dare

Kii ṣe iroyin mọ pe awọn agbabọọẹu ikọ Super Eagles ja ọpọ awọn ololufẹ ere bọọẹu ni Naijiria kulẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye pẹlu Seirea Leone lopin ọsẹ to kọja ati ni ọjọ Iṣẹgun.

Ifẹsẹwọnsẹ naa kun ara ifẹsẹwọnsẹ lati mọ orilẹede ti yoo lọ kopa ninu idije ife ẹyẹ ere bọọẹu ilẹ Afirika, CAN ti yoo waye lọdun 2021.

Ireti ọpọ onwoye ni pe bi ẹni fi ẹran jẹkọ ni yoo ri fun ikọ super Eagles ati pe nigba ti yoo ba fi pari ifẹsẹwọnsẹ onibeji pẹlu orilẹede Serea Leone naa ni ilu Benin ati ikeji rẹ ni Freetown ọna yoo ti la fun un lati tẹsiwaju lọ si idije naa.

Amọṣa, ẹkọ ṣoju mimu fun ikọ Super Eagles. Goolu mẹrin ni wọn ti fi lewaju Serea Leone ni ilu Benin, ki o to di pe awsn agbabọọlu fi ogun ẹyin ja wọn ti wọn si da mẹrẹẹrin pada.

Nigba ti wọn yoo si gba oju keji ifẹsẹwọnsẹ naa ni orilẹede Serea Leone, ọmi ni wọn ta.

Nibayii, minisita ere idaraya, Sunday Dare ti ni, ifẹsẹwọnsẹ mejeeji naa fihan pe muṣemuṣe akọnimọọgba ikọ naa, Genot Rohr ko gba muṣe to ni nitori naa awọn yoo wa wọrskọ fi ṣada lori rẹ.

Loju opo ẹlẹyẹ Twitter rẹ ni o ti sọ ọrọ yii.

O ni ohun to yẹ ikọ Super Eagles gẹgẹ bi ọkan lara awọn alagbara ere bọọlu lagbaye kọ niyi, nitori naa igbesẹ atunṣe yoo waye lọgan.