Iran kéde Alireza Arafi gẹ́gẹ́ bí adelé olórí orílẹ̀ èdè lẹ́yìn ikú Ayatollah Ali Khamenei

Oríṣun àwòrán, Internet

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè Iran ti kéde Ayatollah Alireza Arafi gẹ́gẹ́ bí adelé olórí fún orílẹ̀ èdè náà ṣáájú kí wọ́n tó yan olórí tuntun.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n kéde ikú Ayatollah Ali Khamenei.

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹlẹ́ni méjìdínláàádọ́rùn-ún (88) ló panupọ̀ lórí ìyànsípò Alireza gẹ́gẹ́ bí adelé olórí orílẹ̀ èdè náà.

Ní ọdún mẹ́jọ mẹ́jọ làwọn aráàlú máa ń dìbò láti yan àwọn èèyàn tí yóò wà nípò gẹ́gẹ́ bí aṣòfin tó le yan olórí ìlú.

Lábẹ́ òfin Iran, àwọn ìgbìmọ̀ yìí ló ní àǹfàní láti yan olórí orílẹ̀ èdè lẹ́yìn tí wọ́n bá yọ olórí nípò tàbí tí olórí orílẹ̀ èdè bá jáde láyé.

Àdó olóró Amẹrika àti Israel kọlu ilé ẹ̀kọ́ kan, ṣekúpa èèyàn 148 níbẹ̀ - Iran

Oríṣun àwòrán, Reuters

Orilẹede Iran ti sọ pe ado oloro ti Israel ati Amẹrika ju si orilẹede naa kọlu ile ẹkọ kan, o si ṣekú pa eeyan ti ko din ni 148 níbẹ.

Aarẹ Masoud Pezeshkian sapejuwe ikọlu ado oloro naa gẹgẹ bí eyi to buru ju, tó sì jẹ iwa ọdaran awọn alakatakiti.

Ko tíì si ọkan kan lara awọn orilẹede alagbara lágbàáyé mejeeji ti ọrọ kan to ti sọrọ lori ikọlu si ile ẹkọ naa.

Àjọ Red Crescent ni Iran sọ pe ko din ni eeyan 201 to ti ku kaakiri orilẹede naa latari awọn ado oloro ti Amẹrika àti Israel tí ju si orilẹede naa.

Ajọ naa sọ pe ko din ni eeyan 747 ti wọn ti farapa nitori awọn ado oloro naa.

Àjọ alaanu Red Cross ati ajọ Red Crescent niluu Geneva sọ pe ajọ naa yoo ran awọn oṣiṣẹ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà.

Oṣiṣẹ kan sọ pe bii ado oloro mẹta lo kọlu ile ẹkọ naa to wa lẹkun Hormozgan.

BBC gbé fídíò kan jáde èyí tó ṣàfihàn bi eefin ṣe n yọ lati ori ile naa, lẹyìn tí ikọlu ọhun ṣẹlẹ.

Ni ṣe ni ero pejọ biba níwájú ilé naa pẹlu ipaya ọkan.

Amọ, BBC ko tii le sọ pato iye eeyan to padanu emi wọn ninu ikọlu naa titi di asiko yii.

Awọn alaṣẹ Iran kọ lati fun awọn ileeṣẹ iroyin ni fisa lati rìnrìn àjò lọ sí orileede naa.

Awọn eeyan lori ayelujara ni Iran ti koro oju si iṣẹlẹ naa.

Ọmọbibi Iran kan to n gbe nilẹ okeere tako lilo ológun lórílẹ̀ èdè Iran.

O ni ogójì ọdọbinrin ni Minab lo kọkọ fori ko iṣẹlẹ ikọlu yii.

Àdó olóró Amẹrika àti Israel ṣekú pa adarí orílẹ́èdè Iran Ayatollah Ali Khamenei

Oríṣun àwòrán, @IranTimes9

Ado oloro ti Amérika ati Israel yin ti ṣeku pa adari orilẹede Iran, Ayatollah Ali Khamenei.

Ileeṣẹ iroyin orilẹede Iran sọ pe ado oloro ti Amẹrika ati Israel yin laaarọ ana ọjọ Abamẹta lo ṣeku pa Khamenei.

Aarẹ Donald Trump ni Khamenei jẹ ọkan lara awọn oniṣẹ ibi to buru julọ lagbaaye ninu itan.

Trump wa rọ awọn eeyan Iran lati gba orilẹede wọn pada lẹyin iku Khamenei.

Idunnu ṣubu layọ fun ọpọ eeyan lawọn ilu kan lorilẹede Iran pẹlu iku adari orilẹede naa, nigba tawọn kan si n kẹdun rẹ.

Ẹnikan sọ fun BBC Persia wi pe ile aye yoo tun dara si i ni bayii ti Khamenei ti ku.

Iroyin sọ pe ko din ni igba eeyan to ti ku bayii ni Iran.

Iroyin naa ni o kere tan eeyan mejidinlaadọfa (108) lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti ado oloro Amẹrika ati Israel kọlu ile ẹkọ awọn obinrin kan ni Iran.

Aarẹ Trump ni ikọlu si Iran yoo tẹsiwaju titi ti alaafia yoo fi jọba lẹkun Middle East ati ni gbogbo agbaye.

Iran da padà, bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tó wà ní Middle East

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Iran ti sọ pé àwọn ti ṣèkọlù sí oríko iléeṣẹ́ ọmọ ogun orí omi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó wà ní Bahrain.

Wọ́n ní ìgbésẹ̀ náà ló ń wáyé láti gbẹ̀san ìkọlù tí Amẹ́ríkà àti Israel pawọ́pọ̀ ṣe sí orílẹ̀ èdè wọn.

Níṣe ni èéfí ńlá ṣẹ́yọ ní ẹ̀gbẹ́ iléeṣẹ́ ológun náà tó wà ní agbègbè Manama, Bahrain àmọ́ bí nǹkan ṣe bàjẹ́ tó níbẹ̀ kò ì yé ẹnikẹ́ni, tí ìjọba Amẹ́ríkà kò ì sì tíì nǹkankan nípa rẹ̀.

Bákan náà ní àwọn orílẹ̀ èdè míì ní ẹkùn náà bíi UAE, Qatar àti Kuwait sọ pé àwọn ti ṣe ìdádúró àwọn àdó olóró tí Iran fi ránṣẹ́ sáwọn agbègbè tí iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà wà.

Ní Doha, iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ààbò ní Qatar sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn àdó olóró tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n fẹ́ fi ṣèkọlù sí al-Udeid ni àwọn ti ṣe ìdádúró rẹ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn iléeṣẹ́ ológun mẹ́tàlá ni Amẹ́ríkà ní káàkiri ẹkùn Middle East, tí wọ́n sì ní àwọn ọmọ ogun tó tó 30,000 sí 40,000 níbẹ̀.

Àwọn aláṣẹ ní Bahrain fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìkọlù wáyé sí iléeṣẹ́ ológun orí omi ti Amẹ́ríkà.

Iléesẹ́ ológun Iran, Iran's Revolutionary Guard Corps nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde sọ pé àwọn ohun ìní ati iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tó wà ní agbègbè náà ni àwọn máa ṣe ìkọlù sí, láti fèsì sí ìkọlù tí Amẹ́ríkà àti Israel ṣe sáwọn ní òwúrò ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Ní nǹkan bíi aago mẹ́fà ìdájí ọjọ́ Àbámẹ́ta ni Israel àti Amẹ́ríkà ṣèkọlù sí agbègbè ibití olórí Iran wà, tí Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump sì rọ àwọn èèyàn Iran láti dìde tako olórí wọn.

Ní Israel, níṣe ni ìró ọkọ̀ àwọn ọmọ ogun ń dún lákọlákọ bí iléeṣẹ́ ológun Israel ṣe ní àwọn ṣàwárí àwọn àdó olóró tí Iran fi ránṣẹ́ sí orílẹ̀ èdè àwọn.

Ní Jordan, iléeṣẹ́ ológun ni àwọn ti mú àdó olóró tó fẹ́ wọ orílẹ̀ èdè àwọn méjì bọlẹ̀ àti pé ẹnikẹ́ni kò pàdánù rẹ̀ sọ́wọ́ ìkọlù àwọn àdó olóró náà.

Iléeṣẹ́ ààbò ní United Arab Emirates, UAE sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn àdó olóró láti Iran ló ti balẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn àti pé ọ̀pọ̀ àwọn àdó olóró náà làwọn mú balẹ̀.

Wọ́n ní àdó olóró náà balẹ̀ sí agbègbè táwọn èèyàn ń gbé ní Abu Dhabi tó sì bá ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ àti pé aráàlú kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ ìkọlù náà.

Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní Iran, Abbas Araghchi bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tí Amẹ́ríkà àti Israel ṣe sí wọn bí wọ́n ṣe ní ìkọlù náà kò bá òfin mú àti pé àwọn ti gbáradì fún ọjọ́ òní láti kọ́ àwọn tó ń máa ń ṣe ìkọlù lọ́gbọ́n tó yẹ.

Amẹrika àti Israel pa ọwọ́ pọ̀ ju ọ̀pọ̀ àdó olóró sí Iran

Oríṣun àwòrán, getty

Ijọba ilẹ Amẹrika ati orilẹede Israel ti pawọ pọ lati ju ado oloro si Iran.

Awọn aworan ti BBC foju ri ṣafihan bi eefin ṣe n ru laarin ilu Tehran, to jẹ olu ilu orilẹede Iran.

Lẹyin ikọlu naa ni Aarẹ Donald Trump sọ pe afojusun Washington ni lati dena ikọlu eyikeyi to le waye lati ọwọ Iran.

Minisiti eto abo Israel, Israel Katz ni tirẹ juwe ikọlu naa bii eyii to waye lati dena ikọlu ọjọ iwaju lati ọwọ Iran.

Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe ibugbamu meji ọtọtọ lo dun ni Teharan laarọ ọjọ Abamẹta ti eefin si n ru soke laarin ilu naa.

Ninu fidio kan to fi lede, Trump sọ pe "Ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika ti bẹrẹ ikọlu si Iran.

"A maa ba gbogbo ado oloro misaili wọn jẹ, a si maa sọ ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe misailu di ẹdun arinlẹ.

"A maa pa gbogbo rẹ run patapata. A maa pa ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi wọn run."

Trump tun sọ fun awọn ọmọ orilẹede Iran ọhun pe asiko ominira wọn ti to, o ṣi ṣeleri iku fun awọn ọmọ ogun wọn to ba n ṣe agidi, ati ileri iwalaaye fun awọn to ba ju ọwọ silẹ.

Ẹwẹ, ileeṣẹ iroyin Iran kan sọ pe alaafia ni Aarẹ Masoud Pezeshkian wa lẹyin ikọlu ọhun.

Ileeṣe iroyin Fars jabọ pe ado oloro meje ọtọtọ lo balẹ si agbegbe Keshvardoost ati Pasteur.

Oṣojumikoro kan sọ fun AFP pe "Oju mi mejeji ni mo fi ri ado oloro Tomahawk meji ti wọn n fo… lakọkọ, ariwo ni a kọkọ gbọ, ki a to ri ọkọ ofurufu to n ju ado oloro."

Iran, Iraq ati Israel gbe papakọ ofurufu wọn ti pa lasiko ti ikọlu naa n lọ lọwọ, ọọfisi ijọba Amẹrika to wa ni Qatar ati Bahrain si ti rọ awọn ọmọ Amẹrika to wa lagbegbe naa ki wọn fo ori wọn pamọ.

Ṣaaju ikọlu yii ni ijọba Amẹrika ati Iran ti ni ifọrọwerọ ni Geneva amọ itakurọsọ naa fori ṣọpọn.

Trump sọ lẹyin ipade naa pe ijọba Iran ko tii ṣetan lati fun Amẹrika ni nnkan to n fẹ.