Àwa kọ́ la bẹ̀rẹ̀ ogun pẹ̀lú Iran, ṣùgbọ́n àwa la máà fòpin síi – Hegseth, alákóso ètò àbò nílẹ̀ Amẹ́ríkà
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Amẹrika ti sọ wi pe oun kọ lo bẹrẹ ogun pẹlu orilẹede Iran, ṣugbọn labẹ iṣakoso Aarẹ Trump yoo yanju rẹ.
Alakoso ọrọ abo lorilẹede Amẹrika, Pete Hegseth ṣalaye lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ogun ti Amẹrika ati Amẹrika n gbe koju Iran,
Ọgbẹni Hegseth ṣalaye pe orilẹede Amẹrika ko le e gba ki Iran maa ko nnkan ijaogun oloro Nuklia jọ. O ni Aarẹ Donald Trump ti fa ila o to gẹẹ bayii lori ọrọ naa "lẹyin ti Iran ti ṣe eyi to wu u fun ọdun mẹtadinlaadọta"
O tẹsiwaju lati kilọ pe ẹnikẹni to ba da ẹmi ọmọ ilẹ Amẹrika kankan legbodo ko ni fi ara ire lọ nitori pe wọn yoo wa ẹni bẹẹ kan wọn o si fi ẹmi rẹra ẹmi bi o ti wulẹ o mọ.
Hegeth ṣalaye pe ohun to mu ọpọlọ dani ni pe awọn ijba kan lagbaye bii ti Iran ko gbọdọ ohun ija oloro, Trump dẹ ṣetan lati gbe igbesẹ to yẹ.
Hegseth: Ikọlu to n lọ lọwọ ni Iran ko le di ogun ọlọjọ pipẹ
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alakoso ọrọ abo lorilẹede Amẹrika naa tun sọ fawọn akọroyin pe "bi Iran ṣe n pa irọ to si n ko nnkan ijagun oloro nukilia jọ yii, bi igba to n fi ibọn si agbari wa ni".
O fi kun un pe ikọlu naa ko ni ja si "ogun ọlọjọ pipẹ". Dipo bẹẹ, o ni orilẹede Amẹrika n gbero lati dana sun awọn nnkan ijagun oloro ti Iran ko jọ.
Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Awọn ọmọogun Israel atawọn ọmọogun Hezbolla lorilẹede Lebanon ti ju ọpọlọpọ ado oloro si ara wọn pẹlu bi ogun ti wọn n gbe ti orilẹede Iran ṣe tubọ n fẹju sii.
Lowurọ ọjọ Aje ni orilẹede Israel bẹrẹ si nii fi ado oloro kọlu awọn ibudo to pe ni ibuba awọn ọmọogun Hezbollah lorilẹede Lebanon lẹyin ti ikọ agbebọn naa yin ado oloro si Israel.
Nibayii ileeṣẹ eto ilera lorilẹede Lebanon sọ pe ikọlu Israel si Beirut atawọn ẹkun gusu orilẹede Lebanon ti ṣekupa eeyan mọkanlelọgbọn, ti awọn mọkandinlaadọjọ miran si tun ti farapa.
Ileeṣẹ alaabo orilẹede Israel tun sọ pe awọn ti kọlu ọkan lara awọn agba ọjẹ ẹgbẹ Hezbollah ni ilu Beirut.
Ninu ọrọ rẹ,olori awọn ọmọ ogun ileeṣẹ alaabo orilẹede Israel, IDF ọgagun Eyal Zamir ṣalaye pe ikọlu ti wọn n ṣe si Hezbolla le gba ọpọlọpọ ọjọ.
"A ti bẹrẹ si nii kogun kọlu ikọ Hezbollah,"
"A nilo lati gbaradi fun ija ti yoo gba ọpọlọpọ ọjọ."
Ki lawọn alaṣẹ ijọ ni Lebanon sọ̀?
Olotu ijọba orilẹede Lebanon, Nawaf Salam ti ṣekilọ fun awọn to n ju ado oloro lati ẹkun gusu orilẹede naa pe ki wọn dẹkun ṣiṣe bẹẹ "lainaani ẹgbẹ oṣelu to le wa lẹyin wọn, jiju ado oloro lati ẹkun Lebanon kii ṣe iwa to bojumu rara, iwa to si lee da ẹmi eto abo orilẹede Lebanon legbodo ni, eleyii to n fun orilẹede Israel ni idi to gbọngbọn lati maa kogun ja Labanon."
Bawo ni ija yii ṣe bẹrẹ?
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Iran ni ikọ ọmọogun Israel dojukọ ki awọn ọmọ ogun Hezbollah, ikọ agbebọn kan ti orilẹede Iran n ṣe atilẹyin ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu dọla fun to yin awọn ado oloro si ilu Haifa lorilẹede Israel.
Israel naa da a pada pẹlu ọkan-o-jọkan ado oloro ati ikọlu lati ofurufu. Awọn ẹkun gusu ni Beruit ti wọn jẹ ibuba awọn ọmọogun Hezbolla ni Israel dojukọ atawọn agbegbe to sunmọ papakọ ofurufu ilu naa.
Lẹkun gusu orilẹede Lebanon, ikọ ọmọogun orilẹede Israel ti ṣe ikilọ ṣaaju fun awọn olugbe awọn ilu bii aadọta lo wa nibẹ pe ki wọn fi ibẹ silẹ, ado oloro tun dun nibẹ pẹlu.
Bi o tilẹ jẹ wi pe agbara ikọ Hezbollah ti dinku pẹlu ikọlu ti Israel gbe koju rẹ ni nnkan bii oṣu mejidinlogun sẹyin, amọṣa pẹlu ajọṣepọ to ni pẹlu orilẹede Iran, o di dandan ki wọn fa oun naa wọ̀ wọ ija to n waye laarin Israel pẹlu Iran.
Ninu awọn atẹjade miran ti ikọ ọmọogun alaabo orilẹede Israel fi sita, o ni lara awọn ibi ti wọn kọlu pẹlu ado oloro ni awọn ibudo ikonkan-pamọ-si atawọn ibudo miran kaakiri orilẹede Lebanon.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available