Akọrin Fuji, Shanko Rasheed pàdánù àkọ́bí ọmọ rẹ̀, Jamal

Oríṣun àwòrán, Iam_shankorasheed/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajúmọ̀ olórin Fuji, Atanda Adekunle Rasheed tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Shanko Rasheed ti pàdánù àkọ́bí ọmọ rẹ̀, Jamaldeen Emrys Atanda.

Ní ìdájí kùtùkùtù ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejì, ọdún 2026 ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wáyé.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Shanko Rasheed kọ sójú òpó Instagram rẹ̀, ó ní "kò sí òbí tó gbàdúrà láti fojú sunkún ọmọ láyé ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run."

Ṣáájú ikú ọmọ náà ni Shank ti ń kọ onírúurú àtẹ̀jáde lójú òpó WhatsApp rẹ̀ pé kí wọ́n má gba àwọn ọmọ òun lọ́wọ́ òun.

Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kejìlá ọdún 2025 ni Shank Rasheed ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún méjìlá fún ọmọ náà.

Ta ni Shanko Rasheed?

Ní ọdún 2002 ni Atanda Adekunle Rasheed tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Shanko Rasheed kọ́kọ́ gbé àwo orin jáde tó pe àkọ́lé rẹ̀ ní Shanko.

Láti ìparí ọdún 1999 ló ti ń kọrin kó tó gbé àwo orin àkọ́kọ́ rẹ̀ jáde.

Ní ọdún 2025 ló ṣe ayẹyẹ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tó ti ń kọrin.

Òun ni wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí olùdásílẹ̀ Fuji Scoobydoo àti Makosa Fuji sounds.

Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọdé àkọ́kọ́ tó kọrin Fuji nígbà tó bẹ̀rẹ̀.

Yàtọ̀ sí orin àkọ́kọ́ rẹ̀, ọ̀pọ̀ orin ni Shanko Rasheed ti gbé jáde, tó sì ti gba àmì ẹ̀yẹ lọ́pọ̀lọpọ̀.

Shanko Rasheed ti gbé ìyàwó tó sì ti ní ọmọ mẹ́ta.