Kò sí inúnibíni sáwọn Kristẹni ní Naijiria, ìjọba fèsì sí ìmọ̀ràn Amerika tó ní Naijiria ní láti fagilé òfin Sharia
Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bola Ahmed Tinubu/X
Ijọba apapọ tun ti sọ pe ko si inunibini sawọn kristẹni ni Naijiria, lẹyin ti ile aṣofin Amẹrika pari iṣẹ iwadii rẹ lori ohun ti wọn pe ni ipaniyan awọn kristẹni ni Naijiria.
Minisita fun eto iroyin, Mohammed Idris, lo fidi ọrọ yii mulẹ lẹyin abọ iwadii igbimọ ile aṣofin Amẹrika lọjọ Iṣẹgun.
Oṣu meji ni igbimọ ile aṣofin Amẹrika naa fi ṣe iwadii lori ọrọ awọn kristẹni ti wọn lawọn alakatakiti n ṣeku pa ni Naijiria.
Igbimọ ile bẹrẹ iwadii ọhun lẹyin ti Aarẹ Donald Trump kede wi pe ọrọ Naijiria n kọ oun lominu tori nnkan to n ṣẹlẹ sawọn kristẹni nibẹ.
Lẹyin naa ni Trump kepe aṣofin Riley Moore ati Tom Cole wi pe ki wọn ṣewadii iṣekupani ati ṣiṣe inunibini sawọn kristẹni ni Naijiria.
Aṣofin Moore sọ ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ pe abọ iwadii awọn ṣafihan ipari iṣẹ ti Trump gbe lawọn lọwọ naa.
Amọ, minisita eto iroyin sọ ninu esi rẹ wi pe ko si nnkan to jọ ṣiṣe inunibini sawọn ẹlẹsin kan tabi omiran ni Naijiria.
Ṣugbọn orilẹede Amẹrika naa duro lori ẹsẹ wọn pe awọn alakatakiti ẹsin n ṣeku pawọn kristẹni.
Idris sọ pe ijọba apapọ ti n ṣe agbeyẹwo awọn imọran to wa ninu abọ iwadii igbimọ ile aṣofin Amẹrika lori ṣiṣe inunibini sawọn kristẹni ni Naijiria.
''Naijiria ṣetan lati tẹle imọran ti ko ba ni tako iwe ofin orilẹede wa''
''Ijọba apapọ mọ pe awọn ẹkun kan wa ti eto aabo ti mẹhẹ, latari awọn agbesunmọmi atawọn agbebọn ti wọn n ṣoṣẹ nibẹ.
Ijọba si n kọminu lori bi ẹmi awọn eeyan ati dukia olowo iyebiye ṣe n ṣofo lawọn ẹkun naa.
A ba gbogbo ẹbi tawọn eeyan yan ti padanu ẹmi wọn kẹdun lai fi ti ẹsin tabi ti ẹya kan ṣe, latari iṣẹ laabi awọn agbesunmọmi.
Amọ, o ṣe pataki lati fidi rẹ mulẹ pe ko si inunibini sawọn ẹlẹsin kankan ni Naijiria.
Iṣoro eto aabo ti Naijiria n koju ko ni nnkankan ṣe pẹlu ẹsin tabi eto ijọba kan, bi ko ṣe awọn ọdaran atawọn agbesunmọmi to n da omi alaafia ru ni Naijiria,'' minisita eto iroyin lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Idris ṣalaye siwaju sii pe iwe ofin orilẹede Naijiria fun araalu lominira lati ṣe ẹsin to ba wu wọn.
O ni ijọba ko ni beṣu bẹgba lati ri pe ko si ẹni to tẹ ẹtọ ẹnikankan mọlẹ.
Minisita eto iroyin ni Naijiria ṣetan lati tẹle imọran ti ko ba ni tako iwe ofin orilẹede Naijiria.
O ni Naijiria yoo tẹsiwaju pẹlu ibaṣepọ ọlọjọ pipẹ to ni pẹlu orilẹede Amẹrika.
Lara imọran to wa ninu abọ iwadii igbimọ ile aṣofin Amẹrika ni pe Naijiria ni lati fopin si ofin ṣharia tawọn ipinlẹ kan n lo lẹkun ariwa Naijiria ati bẹẹ bẹẹ lọ.
'Nàìjíríà lorílẹ̀èdè tó léwu jùlọ fún kristẹ́nì láti gbé lágbáyé' – ilé àṣòfin Amẹ́ríkà gbé èsì ìwádìí nípa ìṣekúpa àwọn Kristẹni ní Naijiria jáde
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump, ti tẹwọ gba ẹkunrẹrẹ alaye nipa iwadii bi ọpọ awọn ẹlẹsin Kristi ṣe n padanu ẹmi wọn lẹyin ọpọ oṣu iwadii lati ọwọ aṣofin ile igbimọ aṣofin Amẹrika.
Esi iwadii yii ni awọn ọmọ igbimọ tẹẹkoto lori ọrọ iṣuna ati ọrọ ilẹ okeere nile aṣofin orilẹede Amẹrika , fi ransẹ si ile ààrẹ Amẹrika, pẹlu alaye ati imọran ti wọn ni fun iṣoro to n koju awọn Kristẹni ni orilẹede naa.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti Trump ṣapejuwe orilẹede Naijiria gẹgẹ bii orilẹede to ni ohun woye pe o nilo amojuto gboogi, to si pa a laṣẹ fun awọn ọmọ ile igbimo aṣofin, Riley Moore ati Tom Cole lati gbe fimu finlẹ lori ohun to n ṣẹlẹ nipa eto aabo orilẹede Naijiria.
Ki ni abọ iwadii US?
Moore fidi rẹ loju opo X rẹ lọjọ Aje, pe ipade waye lori iwadii naa, ti wọn si ti gbe esi iwadii lọ ile ijọba, White House.
Gẹgẹ bii o ṣe ti ṣe sọ, Moore ni iwadii naa lo lori ero awọn onimọ ati awọn oṣojumikoro pẹlu iranlọwọ lati ọdọ awọn ijọba Amẹrika.
Ṣaaju ni Moore lewaju awọn igbimọ wa si orilẹede Naijiria ti wọn si ṣe abẹwo si awọn agbegbe kan ni Naijiria, awọn eeyan ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si sọrọ, ni ipade pẹlu awọn olori ijọba, to fi mọ oludamọran si aarẹ lori aabo, Nuhu Ribadu.
O ni awọn awọn igbimọ naa ti ni oye nipa ohun to n fa kudiẹkudiẹ eto aabo ni awọn apa ibi kan ni orilẹede Naijiria.
"Orilẹede Naijiria jẹ ibi to buru fun Kristẹni lati gbe. Awọn Kristẹni n koju iṣekupani lati ọwọ agbebọn Fulani ati awọn ikọ agbebọn mii, ti wọn si n pa ọpọ awọn Kristẹni, to fi mọ awọn pasitọ ati alufa.
"Didana sun ile ijọsin, ile ẹkọ ati jiji ọpọ gbe wa lara awọn nnkan ti awọn Kristẹni n koju."
Ki awọn imọran ti wọn fun ijọba?
Moore ninu alaye iwadii pe ajọsepọ laarin ijọba Naijiria ati orilẹede Naijiria lati pese aabo to peye fun awọn agbegbe ti Kristẹni wa, ti wọn si gbe ogun t tako awọn agbebọn yii.
Lara awọn imọran ti Moore fi sini esi iwadii naa ni pe ijọba orilẹede Naijiria yoo nilo lati ri pe wọn fopin si ikọlu awọn agbebọn nipasẹ lilo iranlọwọ igbalode ati igbigba awọn agbẹ laaye lati ni idanilẹkọọ lati da abo bo ara wọn.
"Ijọba ni lati ṣe iranlọwọ fun awọn agbẹ to n sin nnkan isin, ki wọn si faye gba awọn agbẹ lati ma da aabo bo ara wọn lọwọ agbebọn.
"Ijọba ni lati gba awọn oṣiṣẹ kun awọn ileeṣẹ ologun, ti wọn yoo ji pepe lasiko ikọlu awọn agbebọn.
"Ijọba lati pese ofin ti yoo fi ijiya fun ẹgbẹ tabi ijọ to n kopa ninu iwa ti ko faye gba ominira ẹsin ṣiṣe."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Kí ló ti wáyé sẹ́yìn nípa eto aabo Nàìjíríà laarin ààrẹ Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà?
Lọdun to kọja ni ijọba ilẹ Amẹrika kede pe oun yoo gbẹsan lara ijoba Naijiria tori bo se kuna lati daabo bo awọn Kristẹni.
Aarẹ Amẹrika tun fi orukọ Naijiria si ara awọn akọsilẹ orukọ awọn orilẹede to tapa si ofin ominira lati ṣe ẹṣin to ba wu onikaluku.
Bakan naa, ninu oṣu Kejila ọdun 2025, ijọba Amẹrika tun kede ilẹ Naìjiria bii ara awọn orilẹede ti yoo nira fun lati wọ orilẹede naa, to si fi ofin ati gbedeke ti irinajo awọn ọmọ Naijiria si Amẹrika nidi.
Bakan naa ni ikọ ologun Amẹrika kọlu awọn agbegbe kan ni orilẹede Naijiria lọdun to kọja.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available