World Cancer Day: Ènìyàn 26,000 ni àìsàn jẹjẹrẹ ń pa lóòjọ́
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ Eto Ilera Lagbaye, WHO ti pe akiyesi awọn eniyan si ipa ti aisan jẹjẹrẹ n ko lawujọ, pẹlu akiyesi pe miliọnu mẹjọ eniyan ni yoo ku lọdun yii nipa aisan jẹjẹrẹ.
Ajọ Agbaye to ni akọri ti ọdun yii ni 'I am and I will', fikun wi pe ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn eniyan lo n ku lojoojumọ nitori aisan jẹjẹrẹ.
Ajọ naa fikun wi pe o ṣeeṣẹ ki o peleke si ninu ọdun yii pẹlu bi oju ọjọ ṣe n bajẹ si, ti igbe aye awọn eniyan o gbe pẹẹli si ati iru ounjẹ ti awọn eniyan n jẹ.
Kini awọn nkan to n fa aisan jẹjẹrẹ?
- Ọjọ ori
- Gbigbe igbe aye inira
- Fifi taba lile ati oti mimu
- Aisan inu ara
- Sisanra lasanju le fa aisan jẹjẹre ọmu, ikun ati isalẹ inu pẹlu aisan jẹjẹrẹ ile ọmọ.
Kini ọna abayọ si aisan jẹjẹrẹ
- Ẹ ṣọra fun fifi taba
- Ẹ jẹun ti ohun ṣe ara loore
- Ẹ jẹ ọpọlọpọ eso ati ẹfọ.
- Ẹ sọra fun sisanra lasan ju
- Ẹ ma mu oti la muju.
- Ẹ sọra fun jije ẹran ti wọn ti ṣe sibẹ tabi ti wọn ti fi sinu ike.
- Ẹ ma a se ere idaraya pẹlu igbe aye to ni itumọ.
- Ẹ ṣora fun oorun osan gangan, pelu aṣo to bo ara.
- Ẹ ma lo si ile iwosan fun abere aje sara lati dena aisan bii Hepatitis B ati bee bee lo.
- Ẹ ṣora fun ibalopo ai lo roba idaboobo.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available
{{rankTranslation}}