Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ọọfisi ijọba Naijiria to wa ni Bahrain ati Kuwait ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ naa pe
Ki wọn maa ṣọra, ki wọn si tẹle gbogbo ilana ati ddabo ara wọn nibẹ
Ikilọ yii ko ṣẹyin bi Iran ṣe n ju ado oloro sibẹ latari ogun rẹ pẹlu Israel ati Amẹrika
____________________________________________
Eemo meeriri
Ọkunrin kan ti ṣekupa ẹgbọn rẹ niluu Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí to wa nipinlẹ Oyo, lẹyin to ni o yinbọn fun oun loju ala
Ọlọpaa ni ṣe ni Lateef Suleiman fi okuta fọ ori ẹgbọn rẹ to si fẹsẹ fẹ lẹyin naa
Awọn ara adugbo gbiyanju ati doola ẹmi arakunrin ọhun, amọ o ti dakẹ ki wọn to gbe dele iwosan
Ẹkunrẹrẹ wa loju opo wa
___________________________________________
Ijọba Amẹrika ti kede orukọ ọmọ ogun rẹ mẹrin to ti ba ogun Iran lọ
Ibudo ologun ti awọn eeyan naa wa ni Port Shuaiba, lorilẹede Kuwait, ni ado oloro Iran ti gbẹmi wọn
Ti o ba fẹ mọ ẹkunrẹrẹ