Samo Baba: Eléréepá ní mi láti kékere, ẹjọ́ sí pọ̀

Àkọlé fídíò, Éégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!

Akẹkọgboye ni Samo Baba ninu imọ Eko Tiata eyi to n jẹ Performing Arts ni fasiti ilu Ilorin.

Seun Abolarinwa to jẹ eegun to wa nidi yiyi ohun ere Bollywood pada si ede Yoruba sọ bo ṣe n ṣe e fun BBC Yoruba to fi n jade ni ọna ti awọn eniyan fẹran.

Awọn miiran ni awọn maa n gbagbe iṣoro wọn ni gbogbo igba ti wọn ba ti wo fọnran rẹ.

Bo ṣe mu ọgbọ́n yii jade kii ṣe bíi ti gbogbo oṣere Tiata bo tilẹ jẹ pe imọ ẹkọ yii lo kọ ni fasiti, Seun sọ pe iṣẹ ti oun n ṣe yii gba ọpọlọpọ ọgbọn ati akoko.

O le mu u kiri mọ inu ibi kọlọfin kan nigba miiran lati ri i pe iṣẹ di ṣiṣe. Ṣugbn lai wo ipenija wọnyii, ọgọọrọ eniyan to ti n tẹle e lawọn oju opo ayelujara rẹ ko lonka.

Fun iru ara ọtọ iṣẹ ọpọlọ yii, gbogbo awọn ololufẹ rẹ loju opo instagram Samo Baba Comedian ko le ṣai ma kan sara si i bi wọn ṣe ni o n paronu rẹ laye awọn ti iṣ rẹ si da yatọ.