COZA: Àdúrà kò le pa ìfipábánilòpọ̀ rẹ́, àtàwọn àkọlé mìí tó jẹyọ lórí ọrọ Fatoyinbo

Awọn eniyan ko ara wọn jọ lati fẹhonu han ni ẹka ijọ COZA ni ilu Abuja ati Eko.

Àkọlé àwòrán, Ara wa kii ṣe nkan iṣere yin, a kọ ifipabanilopọ
Àkọlé àwòrán, Tọkunrin-tobinrin lo pejọ sibi iwọde naa
Àkọlé àwòrán, Iwọde naa fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ loju ọna Mobolaji Bank Anthony, Ikẹja nibi ti ijọ COZA wa l'Eko
Àkọlé àwòrán, Obinrin yii n sọ pẹlu akọle ọwọ rẹ pe 'ẹ maa gba awọn obinrin gbọ
Àkọlé àwòrán, 'Adura ko le pa ifipabanilopọ rẹ.'
Àkọlé àwòrán, Ẹ ma fi orukọ Ọlọrun daabo bo afipabanilopọ
Àkọlé àwòrán, Sọrọ sita lasiko yii, ma pa ẹnu rẹ mọ ti wọn ba fi ipa ba ọ l'opọ.
Àkọlé àwòrán, Aṣọ funfun ni awọn to fẹhonu han wọ lati polongo tako ifipabanilopọ
Àkọlé àwòrán, Bi wọn ṣe n sọ pe Pasitọ ko ga ju ofin lọ, ni wọn pe iwọ ko gbọdọ fi ipa banilopọ.
Àkọlé àwòrán, Fọfọ̀ ni ẹnu ọna ẹka ijọ COZA to wa ni ilu Eko kun fun awọn to n ṣewọde pe ki Pasitọ̀ Fatoyinbo fi ipo rẹ silẹ
Àkọlé àwòrán, Ọ̀kan lara awọn akọle yii n sọ pe didaabo bo ẹni to fi ipa banilopọ kii ṣe iwa Kristi
Àkọlé àwòrán, Pasitọ kii ṣe Ọlọrun; Ọlọrun le dariji ọ l'ẹwọn